Àṣàyàn Olóòtú Ewì

Ṣé Òmìnira Nì Yìí? | Bakare Wahab Taiwo

A fẹ́ á jẹ máà fẹ́ á yó,
Tó ń fúnni lóko ìdí ọ̀pẹ ro.
Mo gbédìí fórílẹ̀-èdè,
Tó sọ̀yà dohun àjẹsùn fáráàlú.
Wọ́n fẹ́ kéèyàn ó jẹ,
ṣùgbọ́n wọ́n dógò sígi imú wọn,
Wọn ò fẹ́ wọ́n ó yó.
Ìyà ò tóyà lọ̀rọ̀ yìí,
Àfi bíi tọdẹ afàdá pakún…

Etí wo ní í gbọ́ kíjọba máa dẹ pàkúté ikú,
Fún mẹ̀kúnnù láìròó wò!
Ọmọdé,àgbà,oyún-unnú àtàṣẹ́ẹ̀bí,
Nìjọba ń kán ní Kóńdó ìyà lórí,
Láìro tamùjẹ̀ ẹni tí yóò ru.
Èwo ni ká fẹ́ ṣeni lóore,
Kó tún mú páńpẹ́ ikú lọ́wọ́!
Gbogbo ayé ò sùn mọ́,
Tọmọdé tàgbà ní í jí láfẹ̀ẹ̀mọ́júmọ́.
Arọ,adití,wèrè náà kúkú kópa,
Nítorí wọn ò mohun ọ̀la le bí.

Ìyá ń fi ìyà jọmọ,wọn ò jẹ́ wọ́n sùn dájú ṣáká
Ọ̀lẹ̀ ń kígbe àìróorun sùn níkùn.
Ọkọ àtìyàwó dọlọ́dẹ láàjìn;
Ní bí wọ́n ṣe gbéná síwájú orí,
Bíi tàjẹ́-ọdẹ tó mọṣẹ́ẹ rẹ̀ níṣẹ́.
Ọ̀pọ̀ tó fojú rẹ́bọ ò ṣeé kà!
Òtútù á múni bí ẹni wọ́n domi yìnyín lù.
Ẹ̀dá tó fojú gán-án-ní abara-méjì ò délé wí.
ṣé bórí ṣe gbá lọ́gán náà ló fẹ́ sọ ní,àbí bóo?
Wọ́n fọ̀rọ̀ ṣọ̀rọ̀ ọmọdé tó rààtàn fọwọ́ kómí.

Pópó ń ṣe ṣọ̀kọ̀ṣọ̀kọ̀ bí ọbẹ̀ ìyá àgbà.
Alùpùpù ń já firífirí lọ́tùn-ún lósì.
Ọlọ́kadà dolówó lẹ́nu ọ̀rọ̀ náà.
Dírẹ́bà iwájú ilé tí ò rówóolé san,
Donípẹ̀tẹ́sì mẹ́fà láàárín ọjọ́ péréńte.
Hùn! ṣọ́rọ̀ yìí àbómìíràn?
Ilé ayé ń kánjú!
Ẹ̀dá inúu rẹ̀ ń sá kíjo-kíjo.

Lẹ́yìn títò lórí ìlà fódindi wákàtí mẹ́wàá,
Lórí pé a fẹ́ gba nọ́ńbà "NIN",
Pàbó ni tọ̀pọ̀ já sí.
ṣé kì ń ṣe pé owó fọ́ọ̀mù wọgbó nù-un?
Lẹ́yìn gbogbo èéfín ẹ̀rọ-ìtanná tí kóówá fín símú.
Ọ̀pọ̀ gba kámú,wọ́n kọrí sílé.
Òmíràn pọ̀rọ̀ náà léré,wọ́n lọ́mọdé ló layò.
Wọ́n ní bí "SIM" búlọ́ọ́kù,àgunlá.
Nbí Ìjọba ti pàdí àpò pọ̀ májọ "SIM" gbogbo!

Tí a bá fegbò ṣegbò ilé;
ṣé bíi ká fi dóúnjẹ kọjá ní?
Ìjọba Nàìjíríà,àfi sùúrù.
Ìyà ibẹ̀ níí kúkú kárí.
Mùdùn-múdùn ibẹ̀,àwọn alágbára ló ní í.
Bó ti ẹ̀ máa ro,
Ẹnu àwọn olè tí wọ́n fi ṣajojú ní í ro sí.

Kò dìgbà tá a bá jẹyán,ká tó yán.
Olódùmarè o! Gbà wá lọ́wọ́ ogun Nàìjíríà.
Póńpó ìyà tí ń bẹ lọ́wọ́ wọn,
Kìí ṣohun tó yẹ kéèyàn gbà sórí.
Bó tiẹ̀ sàn fẹ́ni ó nírun lórí,
Kí wá ni tapárí bíi tigún?
A ò ní jẹ̀yà yìí gbé.
A ó jọ mọmú Nàìjíríà lámubó ni.
Gbogbo àwọn ọ̀jẹ̀lú ayé,
Igbá tá a fi wínkà là á fi í san án.

Nípa Òǹkọ̀wé

Bákàrè Wahab Táíwò jọ́mọ bíbí ìlú Ọ̀gbàgì Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ó jákẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ní Fásitì Adékúnlé Ajásin,Àkùngbá Àkókó,ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè gẹ̀ẹ́sì ló ń kọ àwọn lítíréṣọ̀ Yoòbá.

Related posts

Ẹ̀rín Àríntàkìtì L’ékìtì | Káyòdé Akínwùmí

atelewo

FÍDÍÒ: Ewì Ènìyàn | Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim Àjàtóntìrìàjàbalẹ̀

atelewo

Èèmọ̀ Ní Pópó Àti Ewì Mìíràn|Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀

Atelewo

4 comments

Ameen Abdulwahhab January 9, 2022 at 12:20 pm

Good poem…. Keep it up

Reply
Fagbuyi Adedayo Jamiu my January 9, 2022 at 1:49 pm

E ku ise opolo

Reply
Fagbuyi Adedayo Jamiu my January 9, 2022 at 1:52 pm

E ku ise opolo. Ki Olorun ko was yo. Amin

Reply
Ameen Abdulwahhab January 10, 2022 at 5:43 pm

E ku laakaye,e ku ise opolo pipe…. Iwe dun un nka daradara osi tun kowa leko … Eku ese opolo….. Ogbeni BAKARE TAIWO

Reply

Leave a Comment