À-pè-kánukò

Àpèkánukò!
Àpèṣ'ẹnu ṣùùtì
Bí-i músù ú rẹ́ja nínú ike.
Owó ní í jẹ́bẹ̀, ìwọ ọ̀rẹ́,
Bí kò bá sí nílé,
Ẹ má wúlẹ̀ d'ọ́rọ̀ ọ́ lẹ̀.

Wọ́n ti ní oun t'ówó bá ṣetì,
Ilẹ̀ ní í gbé,
Owó sì l'aṣọ oge,
Owó ní ń múni dara.
Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pa á,
Tor'ówó laní
lafí ń ra oun tó ń m'ọ́bẹ̀ ẹ́ dùn.

Àwọn kan l'ówó ni gbòngbò ẹ̀ṣẹ̀,
Ṣùgbọ́n b'ìfẹ́ owó bá pọ̀ l'ọ́kàn èyàn ni;
Nítor'ígbà náà lẹ̀dá ó máa wáwó lọ́nàkọnà.

Èdùmàrè fúnmi l'ówó,
Jẹ́ n r'ówó lò'ṣẹ̀mí-ire.
Ṣùgbọ́n máfi ṣe gààyà l'órí ẹ̀mí ì mi.
Má f'owó ṣ'ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi,
Má f'owó ṣ'ọ̀tá à mi,
Jẹ́ kó j'ẹ́rú ù mi,
Tí ń má a rán s'ọ̀tún s'ósì.
Àṣẹ àwòrán yìí jẹ́ ti Dion J. Pollard

Ẹ bámi sọ fún Bàbá Ṣàngó
aberuku-nímú-lẹ́nu
p’ọ́jọ́ alẹ́ ni mò ń ké sí,

Olówó F’owó Ra’kú

A kì í sọ fọ́mọdé kó mà dẹ́tẹ̀,
tó bá ti lè dágbó gbé.
A kì í sọ f'ónínárun
kó sinmi ẹ̀pà àt'ìbẹ́pẹ ní jíjẹ.
Ẹ bámi sọ fún Bàbá Ṣàngó
aberuku-nímú-lẹ́nu
p'ọ́jọ́ alẹ́ ni mò ń ké sí,
Nígbàt'íbàjẹ́ ó d'ìbànújẹ́ fun un,
Tí yòò wómi lójú, tí kò ní í rí,
Ọjọ́ náà ní mò ń bẹ̀rù.
Èwo gan l'olówó f'owó ra'kú?
Agbárí ti kún fún tábà, ọkàn èédú;
Ẹò tún jẹ́ kó mọ lórí ẹ̀, ọtí ni ṣá l'ọ̀sán l'óru.
Midinmídìn ò tún jẹ́ ẹ gbádùn,
Ẹ ò tun bu ṣúgà s'ínú ẹ̀wà àt'iṣu mọ́,
Ẹ tún ti ń bu wàrà oníyẹ̀fun sínú u ìrẹsì.
Ikún ń j'ọ̀gẹ̀dẹ̀, ikún ń rẹ́'di,
Ikún ò mọ̀ p'óun tódùn á máa pani.

Págà!
Ṣèbí wọ́n tiní èyàn ò kín bẹ
nínú ilé e rẹ̀ kó fọrùn rọ́,
Oníjė̵kújẹ ẹ̀dá á fọrùn rọ́,
Yóó sì fi gbogbo ara pa.
Ṣèbí wọ́n ní wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ikán ń jẹlé,
bẹ́ẹ̀ n'imú ẹlẹ́dẹ̀ sì ń w'ọgbà,
Ṣùgbọ́n ní'jọ́ tí jẹjėrẹ tí ń jẹ'lé ikán bá dé,
ni ẹ́ ó mọ̀ p'ẹ́lẹ́dẹ̀ ò tó o l'oúnjẹ àárọ̀.
Áńbọ̀sì bọ́sí ẹ̀dọ̀ àti fùkù ara à rẹ.
Jẹjẹrẹ á pa wọ́n lápa s'ínú,
Loóbà d'atóókú-máku,
A-m'ọ̀nà-ọ̀run-málọ,
tí ń wa'wọ́ s'íkú wípé òun n'ikú kàn.

Nípa Akéwì

Táófíkì Ayéyẹmí tí a nífẹ láti pè ní Aswagaawy jẹ́ akọ̀tàn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti agbẹjọ́rò. Àwọn ewì afòyegbé rẹ̀ ń bẹ nínú ìwé kákiri àgbáyé, bí àpẹrẹ Kalahari Review, Nthanda Review, Tuck Magazine, The Quills, Cicada’s Cry, Akitsu Quarterly, Modern Haiku, Failed Haiku, Frogpond, Cattails, Seashores, Presence, The Mamba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́-rẹ̀ gba Àmi Ọ̀wọ̀ nínu ìfigagbága àgbáyé ti Morioka lóri Haiku, 2019.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *