Àgbà

ọ̀pàpà paradà
owó ará ìlú paradà
ó dọbẹ̀ níkùn àgbà
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú wó
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú lu.

ọ̀pàpà paradà
ìpín ará ìlú paradà
ó deépíìnì lẹ́nu àgbà
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú wó
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú lu.

ọ̀pàpà paradà
ààrùn wọ̀lú, ó paradà
ó dowó lọ́wọ́ àgbà
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú wó
wọn jẹ̀lú jẹ̀lú, ìlú lu.

ọ̀pàpà paradà
ó dèèmọ̀ gòdògbò
taani ò mọ̀ pénú àgbà òṣèlú
lèèmọ̀ ti ń gbó
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú.

ọ̀pàpà paradà
ó dèèmọ̀ gòdògbò
taani ò mọ̀ pẹ́nu àgbà ọ̀jẹ̀lú
lèèmọ̀ ti ń tọ́
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú.

ọ̀pàpà paradà
ó dèèmọ̀ gòdògbò
taani ò mọ̀ pọ́wọ́ àgbà òṣèlújẹ̀lú
lèèmọ̀ ti ń so
àgbà òṣèlú, àgbà ọ̀jẹ̀lú.

àgbà, abiinú lu káára bí ajere
jàkùmọ̀ gbélùútà
ọ̀tàlú, ọ̀jẹ̀lú, ọ̀dàlú.

àgbà, abẹẹnu fẹ̀ǹfẹ̀ bí òfò
jàkùmọ̀ gbélùútà
ọ̀tàlú, ọ̀jẹ̀lú, ọ̀dàlú.

àgbà, abọọwọ́ gbọọrọ bí ọ̀ràn
jàkùmọ̀ gbélùútà
ọ̀tàlú, ọ̀jẹ̀lú, ọ̀dàlú.

ọ̀pàpà paradà
ó dèèmọ̀ gòdògbò
taani ò mọ̀ págbàláńgbá
ọ̀tá ìlú lèèmọ̀ gòdògbò
tí ń pàlú lẹ́kún àsùńdákẹ́
Ibí tí a ti rí àwòràn yìí ni YNaija.

Àdán

àdán dorí kodò
ó sùn lọ bámúbámú.

àdán dorí kodò
ó gbàgbé àti wòṣé ẹyẹ.

àdán dorí kodò
ó gbàgbé ìwà.

àdán dorí kodò
ó gbàgbé ìṣe.

ṣebáyé ló dorí kodò
òun làdán fi gbàgbé ìwà.

ṣebáyé ló dorí kodò
òun làdán fi dẹyẹkẹ́yẹ.

Nípa Òǹkọ̀wé

Gabriel Bámgbóṣé jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú Litiréṣọ̀ Aṣàfiwé ní Yunifásítìi Rutgers ní New Jersey. Ó jẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá ati lámèyìítọ́ pẹ̀lú. Òun ni olóòtú àgbàa jọ́nà, Ijagun Poetry Journal. Àwọn ewìi rẹ̀ ti jáde nínú Àtẹ́lẹwọ́ Pélébé, Footmarks: Poems on One Hundred Years of Nigeria’s Nationhood, Ake Review, The Criterion, Lantern Magazine, BareBack Magazine, Journal of Social and Cultural Analysis, The New Black Magazine, Tuck Magazine, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àkójọpọ̀ọ ewìi rẹ̀, Something Happened After the Rain, jáde ní ọdún-un 2014.

A rí àwòrán ojú ewé yìí ni Mezony.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *