“Ẹ jẹ́ kí n gé e jẹ o! Olè, aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ọ̀kánjúwà!” Igbe yìí ni mò ń gbọ́ bí mo ṣe dé ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ti ilé ẹ̀kọ́ gíga fáfitì Ayékòótọ́. Ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀ ni èmi tilẹ̀ pè é, kò kúkú tóṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ibùgbé Ọmọlẹwà. Àpárá akọ ni wọ́n máa ń bá ara wọn dá. Ó sì yà mí lẹ́nu láti rí èrò tì ò pọ̀ bí i omi ní iwájú yàrá mi èyí tí ó fi hàn pé nǹkan ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Ní àkókò yìí, ariwo náà ti dákẹ. Kí ló wá le ṣẹlẹ̀?

“Ẹ kúrò lọ́nà, ẹ jẹ́ kí n kọja. Kí ló ṣẹlẹ?” Ọ̀rọ̀ ajá tó ń gbo ni àwọn èròwòran fi ọ̀rọ̀ mi ṣe, wọn kò dá mi lóhùn rárá. Àfi ìgbà tí ọ̀kan nínu àwọn alábàágbé mi tajú kán tí ó rí mi ni mo tó ó ráyè wọlé. “A mà ti mólè! Àbí ò rí aráalé rẹ ni?” ni ọ̀rọ̀ tí Bídèmí gbé kò mí lójú bí mo ṣe wọlé. Ǹjẹ́ kí n bèèrè pé ta wa ni olé ni mo bá rí Adétọ́lá, ọ̀kan nínú àwọn alábàágbé wa, ní orí ìkúnlẹ́ pẹ̀lú ìkòkò ọbẹ̀ lórí tí ó ń wa omi lójú pòòròpò. Jẹ́síkà, ọmọ warri pọ́nńbèle ò tilẹ̀ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ tí ó fi bẹ́rẹ́ sí ní pariwo pẹ̀lú àdàmọ̀dì èdè gẹ̀ẹ́sì rẹ̀. Ó ní “Ǹjẹ́ o lè gbàgbọ́ pé olòṣì ẹ̀dá yìí ni ó ń jí ọbẹ̀ àti oúnjẹ Bídèmí? Ọbẹ̀ adìẹ tí ó sẹ̀sẹ̀ sè ni ó fẹ́ ẹ́ jí tí ọwọ́ fi bà á. Bí o ti rẹwà tó yìí, o tún ń jalè. O ní ebi ń pa ọ́, a o fún ọ lóúnjẹ? Olójúkòkòrò! À sé ọbẹ̀ ọlọ́bẹ̀ ni o fi ń yọ ẹ̀ẹ̀kẹ́? Tí ò bá kí ń ṣe ti Bídèmí, mi ò bá ti lù ọ́ kán lápá.”

Ẹnu ti mo là sílẹ, mi ò lè pa á dé. Àmọ́ àwọn yorùbá ní agbẹ́jọ́ ẹnìkan dá, àgbà òṣìkà ni. Mo bi Adétọ́là bóyá bẹ́è ni ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ sùgbọ́n níṣe ni ó ń wò bíi mààlúù tí ó rí ọ̀bẹ. Èyí túbọ̀ fi hàn pé ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà. Ọ̀rọ̀ náà ṣe mí ní kàyééfì torí ááyan Adétọ́lá nígbà tí a bá ń bá Bídèmí dárò. Á á bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹ́ èpè kíkankíkan. A ní “Àwọn ọmọ ìrankíran, ọmọ ojú òrọ́lárí.” À ṣé ara rẹ̀ ló ń gbé sépè! Mo wá bèèrè bí wọ́n ti ríi mu. À sé tí a bá ti lọ sí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ láàárọ̀ ni yóò padà wá láti wá da ọbẹ̀ tàbí oúnjẹ náà. Jẹ́síkà tí ó gbàgbé ìwé iṣẹ́ àmúrelé rẹ̀ ni ó wá mú u tí ọwọ́ fi bà á. Ìyẹn sì ti bùn ún ní ìgbájú méjì kí ó tó pe èrò lé é lórí

Mo rántí ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. A sẹ̀sẹ̀ wolé sí ipele kíní nínú ètò ẹ̀kọ́ wa ni. Bí Bídèmí ṣe dé ni ó gba ọ̀nà ọjà lọ láti lọ ra nǹkan ọbẹ̀. Ó se ọbẹ̀ náà, ó fi irú já orí rẹ̀. Ẹja, edé àti ẹran ni ó ṣe ìpàdé nínú rẹ̀. Gbogbo wa ni a sì jẹ nínú rẹ̀. Ohun ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ nígbà tí a dé láti yàrá ìkàwé lọ́jọ́ kejì tí a wá ìkòkò ọbẹ̀ tì. Mo tilẹ̀ rò pé ọ̀kan nínú àwọn eku abàmì tí ó fọ́nká ilégbèé ọmọlẹwà ni. Nígbà tí a rí ìkòkò náà nínú yàrá ìdáná ni a tó ó mọ̀ pé èèyàn ni ó gbé e. Bídèmí kò tilẹ̀ já a kúnra, ó ní ọbẹ̀ náà ti fẹ́rẹ̀ tán tẹ́lè. Ó ní ìtunmọ̀ rẹ̀ ni pé oúnjẹ náà dùn ládùnjù ni. A pinnu láti máa ti ìlẹ̀kùn wa nígbà gbogbo. A sì fi ọ̀rọ̀ náà ṣàwàdà títí oorun fi gbé wa lọ.

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ yìí kò tán síbẹ̀. Ìrẹsì ni wọ́n tún gbé ní nǹkan bí i ọ̀sẹ̀ méjì sí i. Nígbà yìí ni a tó ó mọ̀ ọ́ lọ́ràn. Àwọn yorùbá sì ní làpálàpá ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀tẹ̀, ẹni tó bá ní ifo lọ́rùn kó kíyè sí i. A fi tó àwọn alákóso ósítẹ́ẹ̀lì letí, wọ́n sì ṣe ìlérí láti tú iṣu dé ìsàlẹ̀ kòkò. Gbogbo akitiyan wọn ló já sí pàbó nítorí kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún jí ẹ̀wà àdàlú jẹ. A kò tilẹ̀ rò pé ará ilé ni nítorí kò sí ẹni tí ó máa ń jẹ ẹ̀wà nínú wa àfi ẹni tí ó sè é. Ohun tí ó ń kọ gbogbo wa lóminú ni pé ó ṣe jẹ́ ọbẹ̀ Bidemi nìkan ni wọn ń jí? Kò sí ẹni tí ó lè dáhùn ìbéèrè yìí àfi olè náà.

Adétọ́là kò dákẹ́ ẹkún bẹ́è ni Jẹ́síkà kò dákẹ́ àròyé. Tòun tẹnu ẹ̀ ni àwọn agbófinró Ọmọlẹwà dé tí wọ́n sì gbé é lọ. Híhó ni àwọn èrò ń ho lé e lórí. Ojú sì gbà mí tì fún un. Mo wá rántí ọ̀rọ̀ ìyá mi àgbà “Èéfín ni ìwà, bí a bá bò ó mọ́lẹ̀, á rú. Ìtẹ́lọ́rùn ṣe kókó láyé ọmọ ẹ̀dá. Rántí ọmọ ẹni tí ìwọ ń ṣe. Lóòótọ́, a kò là ṣùgbọ́n a kò ṣ’agbe. Bí o bá nílò ǹkankan tí àwọn òbí rẹ kò tí í ní, pè mí kí o bèèrè. Tí n ò bá ní i lọ́wọ́, mà á wá a yá. Má ṣe mú nǹkan oníǹkan mọ́ tìrẹ o, èmi ò bí olè lọ́mọ o. Orúkọ rere sàn ju wúrà àti fàdákà lọ.” Òótọ́ ni pé ìwà rere lẹ̀sọ́ ènìyàn!


Ọlájùmọ̀kẹ́ ọmọ Kọ́lápọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn ṣùgbọ́n ìlú ìsẹ́yìn ni a ti wò ó dàgbà. Ó jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga fáfitì ìbàdàn. Ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó fẹ́ràn láti máa ka àwọn ìwé àpilẹ̀kọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *