Lààlá òfò

La̒a̒làṣe̒ asa̒n

Gẹ̀gẹ̀sì òsì.

Gàgàrà ìyà

Gẹgẹrẹ  la̒sa̒n,

Òfu̒ùtù fẹ̒ètẹ̀

A̒a̒sà ti̒ ò ni̒ ka̒nhu̒n.

Ki̒ni ka̒ ti se’le̒ Ti̒sà yi̒ si̒?

Ile̒ Ti̒sà kìkì imi̒ ẹran.

Ara̒ Ìbàdàn fẹ̒ràn àpọ̒n poo,

Bo̒o ba̒ ni̒wọn lọ̒rẹ̀ẹ̒

Èèmọ̀ loni̒.

Bo̒o ba̒ ba̒wọn rìn

O se kòn̒gẹ̒ ǹkan,

Ìgbe̒raga pẹ̀lu̒ ara̒ Ìbàdàn,

Ọmọ ìyà niwọ̒n.


Bi̒ Gàm̀bàri̒ se jẹ̒ si̒ Sa̒ba̒ru̒mọ̒.

Kò si̒ bi to̒o gbà wọ̀lu̒ Ìbàdàn

Kìkì ẹ̀gbin,

Kò si̒gbà to̒o de̒ Ìbàdàn

Kìkì ìdọ̀ti̒.

Ètò Ìbàdàn wọ̒ o̒ japa̒ aja̒ lọ

Oju̒ kọ̒tà to̒ ti di̒pẹtà

Kò mọ ni̒wọ̀n egbèje,

Ile̒ ti̒wọ̒n ti sọ dile̒ ilẹ̀

Ìyan ò mọ ni̒wọ̀n ẹgbẹ̀fà.

Bo̒o ba̒ ṣe n̒ wọ̀lù Ìbàdàn,

Oni̒jìbìtì ni o̒ ki̒ ọ ka̒àbọ̀

Bo̒o ba̒ ti n̒ wọ̀l̒u Ìbàdàn

Jàgùdà ni o̒ gbẹrù lọ̒wọ̒ rẹ.

Wọn a̒ ni̒ ko̒o wa̒

Wọ̒n a̒ ni̒ o gbe̒un to̒o gbe̒ lọ̒wọ̒ wa̒.

Ṣe̒ tàsẹtàsẹ lọka̒ n̒ rìn

Òku̒’dìẹ kan ò gbọdọ̀ ro̒ju̒ ba̒la̒patà rẹ̀ jiyàn

Òku̒ eerin kìi̒ ro̒ju̒ bọ̒dẹ wi̒jọ̒.

Ọ̀gà pẹ̀lu̒ ori̒siri̒si àwọ̀

Ìbàdàn pẹ̀lu̒ ori̒siri̒si


Àwọn ọlo̒jà oju̒u ti̒tì n̒kọ̒

Tiwọn ò ṣe̒e̒ wi̒.

Àwọn to̒ n̒ pàtẹ si̒ sọ̒ọ̀bù àlàpà,

Ti wọn ò se̒e̒ fẹnu sọ.

Bo̒o ba̒ wọ mi̒ki̒rà o gbe̒

Bo̒o ba̒ wọ ka̒àbù o sì wọ̀,

Ẹran ajiyọ̀ a dẹran ori̒ ori

Ẹran ajiyọ̀ a dẹran òòrì.

Wèrè ọ̀sa̒n,

 Apanijẹun ààjìn kò ni̒ye,

Wọ̒n n̒ gun àkìtàn lọ̒sàn-a̒n,

Wọ̒n n̒ gun mọ̒tò lo̒ru.

Tàwọn oni̒ba̒a̒rà Ìbàdàn lo̒ semì nì kàye̒e̒fì,

Wọ̒n pọ̀ ju yanrìn òkun lọ.

Bo̒o se n̒ rẹ̒ni to̒ ge̒ lọ̒wọ̒,

Bẹ̒ẹ̀ loo̒ re̒èyàn to̒ yọ lo̒ju̒.

Ìbàdàn ni mo ti ra̒fo̒ju̒ ala̒a̒gànna̒,

Ìlu̒ Ògu̒nmọ̒la̒ ni mo ti ra̒ka̒yi̒n to̒ n̒ ta gu̒gu̒ru̒,

Ìlu̒ La̒gelu̒ ni mo ti ra̒diti̒ to̒ n̒ ta re̒di̒ò.

Bo̒orun ba̒ ràn nI̒bàdàn

A dàbi̒ ẹni pa̒ye̒ fẹ̒ẹ̒ jo̒na̒,

Bo̒jò ba̒ rọ̀ lO̒lu̒yọ̀le̒

A dàbi̒ ẹni pa̒ye̒ fẹ̒ẹ̒ pare̒.

Lọ̒du̒n 2011,

Àwọn ara̒ Apẹtẹ ni ẹ bi.

Ìbàdàn pẹ̀lu̒ ori̒siri̒si.


Se̒ bo̒ri̒ ba̒ se mọ ni̒i̒ see̒ fọ̒ olo̒ri̒,

Bo̒mi ba̒ pọ̀jù

 Dandan ni ko̒ pa̒ olo̒mi lo̒ri̒.

Ni̒ ti di̒da̒ra,

Ẹyẹ ti̒ o̒ ṣe bi̒ ọ̀ki̒n ò si̒ ni̒gbo̒.

Ni̒ ti ni̒ni̒ èèyàn Pàtàkì,

Ẹyẹ ti̒ o̒ dori̒kodò bi̒ àda̒n ò si̒

Ìbàdàn kọja̒ kàsi̒àrà

Ìbàdàn kọja̒a̒ ka̒si̒robo.

Ni̒ gbogbo ilẹ̀ yi̒

Ìlu̒ to̒ la̒gba̒ra bi̒ Ìbàdàn kò si̒.

 À fi ta̒a ba̒ fẹ̒ẹ̒ pàfi̒n la̒du̒bi̒àra̒n fu̒nraa wa.

Ìbàdàn sunwọ̀n ni̒lùu̒

Àwọn ọmọ Ìbàdàn ya̒a̒yì le̒èyàn.

Sùgbọ̒n bi̒ ọmọ Do̒o̒go̒ se da̒ra to̒

Itọ̒ ti̒ ò ni̒ ga̒re̒èjì lo̒ bàwọ̒n jẹ̒,

Bi̒ ọmọ Bìa̒fu̒rà ṣe sunwọ̀n to̒

Wi̒wonkoko mo̒wo̒ ni jàkùtẹ̀ wọn

Kèèta lo̒ bọmọ Yorùba̒ jẹ̒,

Bi̒ Ìbàdàn ṣe da̒ra to̒

 À fi ka̒ fi sẹ̒nu ka̒ da̒kẹ̒

Àkàrà ìya̒ ọ̀rẹ̒ ẹ wa.


Ẹ wa̒ o!

Kìi̒ sẹjọ̒ àgbẹ̀
bi̒ mọ̀ǹgu̒du̒ ila̒ ba̒ dalagba̒lu̒gbu̒ odò.

Ògì rọ̀

Ẹ ma̒ rojọ̒ mẹ̒lẹ̒rọ lẹ̒sẹ̀,

Bi̒ Ìbàdàn se dà

Oyu̒n to̒ sẹ̒ ni

Ẹni̒ dami so̒dò

Àtẹni to̒ ru kete ni ẹ jẹ̒ a̒ bi.


Azeez Michael Kẹ́hìndé tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Fẹ́mi Àjàkáyé jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìsẹ́yìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀ ní agbègbè Òkè-Ògùn. Ó jáde nílé ìwé alákọ̀ọ̀bẹ̀rẹ̀ Ládọ̀gán Ìjẹmbà Community Primary School. Lẹ́yìn náà ló tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Anwar-Islam High School, kí ó tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa eré orí ìtàgé àti sinimá.

Ilé ẹ̀kọ́ àgbà Olùkọ́ni Adéyẹmí College of Education (Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilè-Ifẹ̀. Affliated campus) ni ó ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa èdè Yorùbá.  Òun ni olùda̒si̒lẹ̀ ẹgbẹ̒ agba̒sàga ti̒ a mọ̀ si̒ Africulture Renaissance Team. Ara àwọn isẹ̒ ti̒ o̒ ti se ni: Owo̒ Òjijì (Ìtàn Àròsọ 2016), Àjàǹtièlè (ere̒ ori̒ ìtàge̒ 2015), Sàngo̒bìnrin (ere̒ ori̒ ìtàge̒ 2017) Ọjà Emèrè (Sinima 2017). Àwọn ewì ti̒ o̒ ti̒ kọ ni: Omije̒ Ake̒wì, Sàgbàdèwe, Ẹru̒ Owo̒ abbl.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *