egbeonkawe

atelewo

Dara pọ̀ mọn Ẹgbẹ́ Ònkàwé Àtẹ́lẹwọ́

ÀTẸ́LẸWỌ́ jẹ́ ẹgbẹ́ tí a gbé kalẹ̀ láti fi ìmúṣẹ ba àwọn àfojúsùn wọ̀n yìí:
– Láti pèṣè ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ ati ọ̀dọ́ leé máa kopa pẹlú oríṣiríṣi ẹya aṣa àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ẹ
̀kọ́, ìfọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ ati ṣi ṣe ìpàdé déédé.
– Láti ṣe àgbékalẹ̀ ibi tí a ti má ṣe àkọsílẹ̀ ati ìpamọ òye àṣà Yorùbá ìgbà àtẹ̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa.
– Tí ta àwọn èyàn jí sí ìfẹ́ lítíreṣọ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíjẹ kí ìwé lítíreṣọ̀ Yorùbá wà nlẹ̀ fún tità àti ṣíṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ní èdè Yorùbá.
Ní pàápàá jù lọ lórí àfojúsùn kẹta yìí ni a ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ Ònkàwé Èdè Yorùbá.
Ẹgbẹ́ yìí jẹ́ àpèrè tí ó wa fún ẹnikẹni láti ya oríṣiríṣi ìwé lítírésọ̀ Yorùbá fún ìkọ́raẹni àti fún àkàgbádùn gbogbo ènìyàn. Bẹẹni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yíò ni ànfàní àti le máa ṣe ìfọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ lórí oríṣiríṣi ìwé ti wón bá ń kà. Àwọn ànfàni yóòkù ni:
– Láti darapọ mọn ètò ìkọ́nilédè òun àṣà Yorùbá èyí ti ó maa wáyé ni ẹ̀mejì l’óṣù.
– Láti ra àwọn ìwé Yorùbá ni pọ́kúlowó
– Lati d’ọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ó ni ìfẹ́ àṣà bi tìrẹ́
– àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n ki ẹ tó darapọ̀ mọ́n wa, àwọn ìlànà mélòó kan wa láti pamọ́:
– Ọ̀fẹ́ ni ìforúkọsílẹ̀ fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́.
– Ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan yíò ní ànfàní láti láti yá ìwé méjì lẹ́ẹ́kan ṣoṣo ti wọn yíò sì ní ànfàní àti yá òmíràn lọ́gán ti wọ́n bá ti dáa padà.
– Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò ma da àpò méjì àbọ̀ Naira (N500) ni oṣooṣù fún owó ọmọ ẹgbẹ́.
Fún ìwádìí sí wá ju si àti láti fi orúkọ sílẹ̀, ẹ kàn sí 07061282516 | 08169864345 |08102671199.