Lóòótọ́, àwòrán inú fi hàn pé ọkùnrin méjì ni ìyá máa bí ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ọmọ de. Ọkùnrin kan, obìnrin kan ni wọn bí
.

Bàbá afọ́jú kan wà tí ó máa ń kọjá níwájú ilé wa nígbà tí mo wà ní kékeré. Ó dúdú àmọ́ irùngbọ̀n rẹ̀ funfun báláú. Bàbá náà a máa tọrọ owó. Bí ó bá ti ń lọ, a máa ní “apurọ́mọ́ni takoni, Ọlọ́hun má jẹ́ a kò ó. Apurọ́mọ́ni tíí konilójú, Ọlọ́hun má jẹ́ a kò ó.” Ká ní mo mọ̀ nígbà náà ni, àmín-ìn mi ò bá rinlẹ̀ ju bí mo ti máa ń ṣe é lọ, bóyá n ò bá tí sí ní orí ìkúnlẹ̀ pẹ̀lú omi lójú àti apá lára.

“Wá owó mi síta o! Ṣé olè lo fẹ ẹ́ yà? Kòkòrò ojú rẹ un, abẹ ni n ó fi yọọ́!” Bí mọ́mì ṣe ń sọ báyìí ni wọn tún ki bílèèdì bọ̀ mì lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ké too. Bí mo ti ń kérora, bẹ́ẹ̀ ni Táyọ̀, eku ẹdá ń fẹjú mọ́mi lẹ́yìn. Wọ́n ní bí ìyà ńlá bá gbéni sánlẹ̀, kéékèèké a máa gorí ẹni. Mo ti pariwo títí pé n ò mọ̀ nípa owó náà ṣùgbọ́n kò turun kankan lára wọn; ọmọ wọn ti sọ pé èmi ni mo jíi.

Nígbà tí ó pẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀, mo sì gbà inú ilé lọ. Ọ̀rọ̀ ayé mi wá tojú sú mi. Wàhálà tí ò lópin, ìdààmú tí ò ní ìparí ni mò ń bá á yí lójóojúmọ́. Kìí kúkú ṣe pé mọ́mì kọ́ ló bí mi, àwọn ni wọ́n da ẹ̀jẹ̀ sí mi lójú. Bóyá èmi ni mo sì rò bẹ́ẹ̀, bóyá wọ́n ti pààrọ̀ mi nílé ìwòsàn. Àbí irú ìyá wo ni yóò máa gbé ọmọ rẹ̀ sépè láìro ti ìkúnlẹ̀ abiamọ? Àpá ẹgba wọn kò níye lára mi bẹ́ẹ̀ ni wọn ò yé é lò mí ní ìlò ẹrú.

Ọ̀rọ̀ yìí ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀; àti ìgbà tí mo ti gbọ́njú ni mo ti ṣàkíyèsí pé ìyàtọ̀ wà nínú ìhùwàsí àwọn òbí mi si èmi àti ìkejì mi. Ohun tí wọn a rà fún Táyọ̀ láì béèrè, èmi á bẹ̀bẹ̀ kí n tó o ríi gba. Ohun tí ó máa ṣe tí wọ́n á rẹ́rìn-ín sí ni èmi a jẹ ẹgba sí.

Bàbá mi jẹ́ ẹnìkan tí o fẹ́ràn orúkọ rẹ púpọ̀. Ìfẹ́ yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi kórira ohunkóhun tí ó bá lè paá lára. Nínú ìròrí yìí ni ó ti pinnu pé òun ò fẹ́ ọmọbìnrin nítorí wọn á jẹ́ kí orúkọ òun parun. Ìyá mi ni à bá máa pè ní Rúùtù abọ́kọkú; ohun tí bàbá mi bá fẹ́ ni ó máa bá a fẹ́ láìsí àròyé.

Bí ó ti wu Olúwa ni ó ń ṣe ọlá ẹ̀. Lóòótọ́, àwòrán inú fi hàn pé ọkùnrin méjì ni ìyá máa bí ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí ọmọ de. Ọkùnrin kan, obìnrin kan ni wọn bí. Ohun ìyàlẹ́nu ni èyí jẹ́ ṣùgbọ́n kò sí ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe, wọ́n gba kámú. Wọ́n sọ mí ní Bólúwatifẹ́, wọ́n sì sọ ìkejì mi ọkùnrin ní Omotáyọ̀. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni à ń dàgbà síi, àwọn òbí wa kò sì fi pamọ́ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Táyọ̀ jù mí lọ.

Ọjọ́ burúkú, èsù gbomimu ni ọjọ́ tí bàbá mi fi ayé sílẹ̀. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi tí wọ́n rán mi ni. N ò tíì ju ọmọ ọdún méjìlá lọ ní àkókò yìí ṣùgbọ́n wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé bí àwọn ò bá fi ọwọ́ líle mú mi, n ó máa rìrìnkurìn. Wọ́n ní mo pẹ́, gbogbo àlàyé tí mo sì ń ṣe, ẹ̀yìn etí wọn ló gbà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í nà mi. Nígbà tí ó di àkókò kan, n ò lè mú u mọ́ra mọ́, ni mo bá sá. Ilé wa jẹ́ ilé olókè, ní yàrá wọn lókè ni wọn sì ti ń nà mi. Bí mo ṣe sá ni wọn gbá tẹ̀lé mi. Bí wọn tí ń bọ̀ ni wọ́n yọ ṣubú tí wọ́n sì fi orí gba. Wọ́n ni bí a bá ń jà, bíi kí a kú kọ́. Mo lọọgun pe àwọn ará àdúgbò nítorí ìyá mi kò sí nílé, wọn súgbàá ṣùgbọ́n ẹ̀pa kò bóró mọ́; wọ́n ti papòdà kí wọ́n tó gbé wọn dé ilé ìwòsàn.

Mọ́mì sọ pé èmi ni mo pa ọkọ àwọn. Àti ọjọ́ náà ni inú ilé ti gbóná mọ́ mi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kò sí ẹbí tàbí ará tí ó fẹ́ gbà mí sọ́dọ̀ nígbà tí ìyà mi sì wà láyé. Mo rò ó, mo tún un rò. Kò sí ẹnì kankan tí yóò wá mi tí mo bá sọnù. Mo dìde fùú, mo sì gbé ike oògùn aáyán tí ó wà ní abẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi.

“Bolu! Wá wo ẹ̀rọ ìránsọ tuntun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà!” Ìyá tí ó ń ránsọ́ níwájú ṣọ́ọ̀bù mọ́mì ló ń pè mí. Ẹ̀rọ ìránsọ tuntun! Mo wo ike ọwọ́ mi, mo sì wo ẹnu ilẹ̀kùn.

“Oògùn yìí ò lọ ibìkankan”

Ìtọ́ka

  1. Ọ̀rọ̀ Olóòtú: Ìtọ́wò Àkójọpọ̀ Àtẹ́lẹwọ́
  2. Ìlànà fún Ìgbàwọlé: Àtẹ̀jáde Àtẹ́lẹwọ́ Apá kejì
  3. Ẹ̀rọ Ìránsọ | Kọ́lápọ̀ Ọlájùmọ̀kẹ́
  4. Ojúlarí | Rasaq Malik Gbọ́láhàn
  5. Nítàn kí o tó tán | Malik Adéníyì
  6. Lẹ́tà: Ọ̀rọ̀ Kẹ̀kẹ́ | ‘Gbénga Adéọba

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *