
ÀTẸ́LẸWỌ́ jẹ́ ẹgbẹ́ tí a gbé kalẹ̀ láti fi ìmúṣẹ ba àwọn àfojúsùn wọ̀n yìí:
- Láti pèṣè ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ ati ọ̀dọ́ leé máa kopa pẹlú oríṣiríṣi ẹya aṣa àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ẹ ̀kọ́, ìfọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ ati ṣi ṣe ìpàdé déédé.
- Láti ṣe àgbékalẹ̀ ibi tí a ti má ṣe àkọsílẹ̀ ati ìpamọ òye àṣà Yorùbá ìgbà àtẹ̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa.
- Tí ta àwọn èyàn jí sí ìfẹ́ lítíreṣọ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíjẹ kí ìwé lítíreṣọ̀ Yorùbá wà nlẹ̀ fún tità àti ṣíṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ní èdè Yorùbá.
Ní pàápàá jù lọ lórí àfojúsùn kẹta yìí ni a ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ètò Ẹgbé Òǹkàwé Yorùbá nibi tí a tí n yá àwọn èèyàn ní ìwé ti a sì ti máa ń ṣe àpérò lóri àwọn ìwé lítírésọ̀ Yorùbá.
Ìgbà tí ààrùn kó-nílé-gbé-lé Kòrónà (Covid-19) gbà ‘lú kan ni a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ètò ìwé kíkà náà ni orí afẹ́fẹ́ (Zoom). A bẹ̀rẹ̀ ni Oṣù Kárùn-ún ọdun 2020. Tí ẹ bá wo Ìsàlẹ̀, ẹ ó rí àwọn ìwé tí a ti kà àti àwọn ti a ó kà.
Ètò náà wáyé ni gbogbo òpin ọ̀sẹ̀: Ọjọ́ Sátidé (agogo mẹ́sàn-án alẹ́) Ọjọ Ìsinmi (agogo mẹ́san-án alẹ́) lori Zoom link yìí – https://us02web.zoom.us/j/89354508955?pwd=bXVkS2FBVlU2NkVhejJaZkpvR0RpQT09
Tí ẹ bá ní ìbèérè, tàbí ìránnilétí, ẹ kàn sí [email protected] tàbí kí ẹ ké sí RMG tàbí Ọ̀rẹ́dọlá.
ÀTÚPALẸ̀ ÌWÉ TÍ A TI KÀ ÀTI ÀWỌN TÍ A YÓÒ KA
Oṣù | Ìwé |
Ẹ̀bìbí (May) | Ìrìnkèrindò Nínú Igbó Elégbèje (D.O Fagunwa) |
Ẹ̀bìbí (May) | Àgbákò Ni’le Tẹ́tẹ́ (Kọ́lá Akinlàdé) |
Okúdù (June) | Ó le kú (Akínwùmí Ìṣọ̀lá) |
Okúdù (June) | Ìrèké Oníbùdó (D.O Fagunwa) |
Agẹmọ (July) | Ṣaworoidẹ (Akinwumi Isola) |
Agẹmọ (July) | Eégún Aláré (Láwuyi Ògúnniran) |
Ògún (August) | Àja Ló Lẹrù (Oladejo Okediji) |
Ògún (August) | Ẹni Ọlọ́run Ò pa (Olu Owolabi) |
Ọ̀wẹ̀wẹ́ (September) | Ogún Ọmọdé (Akinwumi Isola) |
Ọ̀wàrà (October) | Àtàrí Àjànàkú (Lawuyi Ogunniran) |
Bélú (November) | Báyọ̀ Ajọ́mọgbé (J. Akin Ọmọ́yájowó) |
Ọ̀pẹ́ (December) | Ọ̀rẹ́ Méjì (Afolabi Olabimtan) |
Ṣẹẹrẹ (January) 2021 | Fàbú (Akínwùmí Ìṣọ̀lá) |
Èrèlé (February) 2021 | Ẹfúnṣetán Aníwúrà (Akinwumi Isola) |
Erénà (March) 2021 | Ta L’olè Ajọ́mọgbé (Kola Akinlade) |
Igbe (April) 2021 | Líṣàbi Agbòǹgbò-Àkàlà (E.O Owolabi) |
Ẹ̀bìbí (May) 2021 | Alòsì Ọlọ̀gọ (Kọ́lá Akínlàdé) |
Okúdù (June) 2021 | Olówólayémọ̀ (Fẹ́mi Jẹ́bọdà) |
Agẹmọ (July) 2021 | Ogun Àwítẹ́lẹ̀ (Adebayo faleti) |
Ògún (August) 2021 | Jẹ́ N Lò’Gbà A Tèmi (T.A.A Ladele) |
Ọ̀wẹ̀wẹ́ (September) 2021 | Ogbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ (D.O Fagunwa) |
Ọ̀wàrà (October) 2021 | Ládépò Ọmọ Àdánwò (Ọlánrewajú Adépọ̀jù) |
Bélú (November) 2021 | Ibú Olókun (J.O. Ogundele) |
Ọ̀pẹ́ (December) 2021 | Baṣọ̀run Gáà (Adebayo Faleti) |
̀