Apá Kiní

    Emọ́ kú ojú òpó dí
Eésùn là, o là dànù
Ọ̀pálánbá ọtí èèbó fọ́
Onígbá sọọ́ kò ri sọ
Ta ń mọ bi ọgbọ́n tún ń gbé?
Ta ń mọbi òye kù sí?

Ifálétí ọmọ Àkànbí
Ikú pa gbe, ó paró
Ikú pàlùkọ̀, ó posùn
Ikú pọmọ Fálétí òun Ìṣòlá
Ó pa gbogbo ọlọ́gbọ́n ayé mọ
Àràbà baba Lápàdé
Awo Tàfá,èèyàn Súlè
Àyímọ́ kìí pọlọ́kọ̀.

Níjọ́ Adébáyọ̀ kú
Níjọ́ Fálétí fi wá sílẹ̀
Tó rọ̀run, igí dá ni
Odó kò le è ró póró
Kọ̀ǹkọ̀sọ̀ wọn ò le gbọnra wú
kẹ́wúkẹ́
Màjèsín inú ilé kò le è sunkún ọmú
Níjọ́ Òkédìjí rọ̀run
Igbá ilé wọn ò le lura wọn
Olùkọ́ àwọn àgbà olùkọ́
Odò ìmò tí gbogbo ọ̀mọ̀wé ń pọn
Ọmọ ìṣọ̀lá akọ́nimákùsíbìkan.

Níjọ́ tọ́ ní ọmọ Fálétí kú
Mo ní irọ́ ni,
Mo ní ikú kí ní ń pagbe
tólóko kìí gbọ́ nílé
Mo ní ikú kí ní ń pàlùkò
tọ́lọ́sà kìí gbọ́dẹ̀dẹ̀ mọ̀
Mo ní kú kíní p'ọmọ Àkànbí ẹ wí fúnmi
Pagidarì igí dá.

Apá Kejì

Ìyá tó báṣọ     
ló bẹ́wù
ló bí sòkòtò
Igi àràbà mẹta ló papọ̀dà
L'éwì, l'éré oníṣe, nítàn àròsọ
Ọmọ ìyá ni wọ́n
Ọládẹ̀jọ Ọ̀kédìjì
Onítàn àròsọ olẹ́tẹlẹ̀múyẹ́
Awo Lápàdé, èyan Tàfá
Akínwùnmí Ìṣọ̀lá
Baba ìyálóde
Ọkọ Ẹfúnṣetán
Aníwúrà
Adébáyọ̀ Fálétí
Awo Adébíḿpé Ọ̀jẹ́dòkun
Èyàn sáṣore ọ̀rẹ́ àtàtà
Ìyá tó báṣọ
ló bẹ́wù
ló bí sòkòtò
Ẹ má yà wọ́n
Ẹ má yà wọ́n

Láti ọwọ́ Omidan Kọ́dáolú Tolúlọpẹ́ (Apálará).Akẹ́kọ̀ọ́ àti Olùkọ́ èdè Yorùbá ni Ifásitì Ìbàdán.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *