Igbawole

atelewo

Àsìkò ti tó láti fí iṣẹ́ rẹ yangàn lórí àpèrè Àtẹ́lẹwọ́ (www.atelewo.org)

 

Ẹ káàbọ̀ sí àpèrè Àtẹ́lẹwọ́ níbi tí a ti ń ṣe àfihàn onírúurú ìṣẹ́ ọ̀nà ọ̀rọ̀ eléyìí tí a kọ/sọ ní èdè Yorùbá àti àwọn àwòrán tí ó jẹ mọ́ ìṣe àti àṣà Yorùbá.

Ẹyin náà le fi ìṣẹ́ yín ṣ’ọwọ́ sí wa fún àtẹ̀jáde l’ orí àpèrè wa.
Ṣùgbọ́n ìlú tí kò s’ofin ẹ̀ṣẹ̀ ò sí níbẹ̀. Ẹ wo ìsàlẹ̀ fún ilànà fún ìgbà wọlé:

A.

Àwọn irúfẹ́ iṣẹ́ tí à ń gbà nìwọ̀n yìí:

– Ewì
– Ìtàn àròkọ kúkúrú
– Àpilẹ̀kọ
– Àwòrán
– Ìjomitoro ọ̀rọ̀

B.

Gbogbo ìṣẹ́ tí ẹ fi ń ṣ’ọwọ́ sí wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ojú lowo ìṣẹ́ ti yín alára.

D.

Gbogbo Olùfiránṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi àlàyé díẹ̀ nípa wọn ránṣẹ́ papọ̀.

Àlàyé nípa olùkọ yìí kò gbọ́dọ̀ ju ọ̀rọ̀ igba (200 words) lọ.

E.

Fídíò tàbí ọ́diò lórí ewì, ẹ̀ṣà abbl kò gbọ́dọ̀ ju 20mb lọ.

Ẹ.

Ní ti Àwòrán, kò gbọ́dọ̀ ju 5mb lọ.

F.

Ẹ fi gbogbo ìgbàwọlé yín ránṣẹ́ sì méélì wa ni [email protected].

G.

Fún aláyè síwájú si nípa ohun k’ohun tí ó ní ṣe pẹ̀lú Àtẹ́lẹwọ́, ẹ kàn sí wa ni [email protected] tàbí kí ẹ pé 07061282516.

Ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́