Àṣàyàn Olóòtú Ewì

Ìwà l’ẹwà | Adéṣínà Àjàlá

Ọmọ mí
Mo bá wọn ná'jà Akẹ̀ẹ̀sán
Mo bá wọn pé lọ́jà Orísúnbáre
Ohun mò ń wá di tíntín abẹ́rẹ́ tó sọnù
Mo wẹ'dò mẹ́fà, mo gòkè mẹ́rìnlá
Ó di ìbèèrè lórí àga ahọ́n mí:
Kíló tún wọ́n ju ẹyínjú lọ?

Ọmọ mí àtàtà
Ó ò báá kétí kúrò lápò
Kí o sì jọ̀wọ tákàdá ọkàn rẹ
Fún ọ̀rọ̀ tó ń gbọ́n gègé ọwọ́ mí
Kí omi ọgbọ́n pa òùngbẹ làákàyè rẹ.

Ọmọ mí tòótọ́
Àdésẹwà ò màa rẹ́wà gbé'lé ọkọ?
Fọlásẹwà màa ń rẹ̀ bi òdòdó níbi iṣé?
Bẹ́ẹ̀ Ẹwàáṣògo ti di ẹni ẹ̀tẹ́ l'àdúgbò?

Wọ́n màa ń sọ pé ìwà l'ẹwá
Ẹwà ni ìwà
Bíi èéfín iná igi ni ìwà; kò ṣeé bò.
Má ṣe jẹ́ kí ìwà rẹ ṣe aìsàn
Ọmọ mí ọ̀wọ́n.

Ìgboràn sàn ju ẹbọ rírú lọ.

Adéṣínà Àjàlá kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣègùn òyìnbó ní fáfitì Ládókè Akíntọ́lá ti ìlú Ògbómọ̀ṣọ́. Àwọn isẹ́ lítírésọ̀ rẹ̀ ti jáde ní Nantygreens, Parousia, Praxis, AFAS Review, Eboquills, The Shallow Tales Review, Heart of Flesh, The Wild Word, The Quills, Arts-Muse Fair àti ní ibòmíràn. Adéṣínà wà ní Twitter àti Instagram ní: @adesina_ajala.

Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Rowland Abiodun.

Related posts

Ojú Lọ̀rọ́ Wà, Ète Lètè | Moyọ̀ Ọ̀kẹ́dìji

atelewo

B’ọ́bẹ̀ ẹ bá dùn àti ewì míràn | Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀

Atelewo

Orí | Akínyẹmí Muhammed Adédèjì

atelewo

Leave a Comment