Àṣàyàn OlóòtúEwì

Kí Akọni Tó Di Akọni | Akínrìnádé Fúnminíyì Isaac

Mo lé téńté sórí igi odán
mobojú wolẹ̀ láti wo àwọn
ẹ̀dá tí Elédùmarè dá sílé Ayé
À'teku, à'teye, àti omo adáríhurun
ọ̀rọ̀ ilé ayeé mú mi mín kan lẹ̀.

bó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ẹ̀dá tí ìwà
wọn kò ṣẹé gbọ́ sétí pọ̀ gidi
síbẹ̀ àwọn ẹ̀dá tí wọ́n kọ́
tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ kí wọ́n
tó wá di akọni wá,
bí wọn kò tilẹ̀ pò púpò.

Àwọn èèyàn jànkàn-jàǹkàn
tí wọn kò fi nǹkan tí máa jẹ ba
nnkan tí wọ́n máa jẹ́ jẹ́ kí wọ́n tó fi
ilẹ̀ bora bíi aso àrán.
Àwọn akọni bíi àwọn Bàbá wa
Adébáyò Fálétí,
Akínwùmí Ìsọ̀lá, àti Ọládẹ̀jo Òkédìji.

Àwọn àrò méta tí kìí dọbẹ̀ nù
àwọn tí wọ́n ti da omi síwájú
kí àwa leè tẹlẹ̀ tútù,
àwọn tí wọ́n dòpó èdè Yorùbá mú
kí ó máa báa dojú kejì ojà.
Àwọn tí ó gbé èdè abínibí won
láruge kí ó máa báa fi orí ṣán pọ́n.

Ní orí igi ọdán tí mo lé ténté sí
ni ìrònú ti sọ orí omodé mi kodò:
báwo ni ìbá ṣe dùn tó
tí a bá kọ́ àwọn omo wa
ní èdè abínibí kí wọ́n lè di akọni
bíi àwọn Bàbá wa Adébáyò Fálétí,
Akínwùmí Ìsọ̀lá, àti Ọládẹ̀jo Òkédìji?

Akínrìnádé Fúnminíyì Isaac jé omo bíbí ìlú Modákéké ní ìpínlè Ọ̀sun. Ó jáde ní ilé ìwè gíga ti Ọbáfémi Awólọ́wọ̀ ní ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ó féràn láti máa kọ ewì àti láti máa kàwé

Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Cleveland State University African Art Collection.

Related posts

B’ọ́bẹ̀ ẹ bá dùn àti ewì míràn | Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀

Atelewo

Ìwà l’ẹwà | Adéṣínà Àjàlá

atelewo

Ṣé Òmìnira Nì Yìí? | Bakare Wahab Taiwo

Atelewo

Leave a Comment