Bí aré kò bá tó aré a kì í pòwe, bí ọ̀rọ̀ kò bá tọ́rọ̀ a kìí fìtàn balẹ̀, bí iṣẹ́ kò bá le a kì í bẹ ọ̀wẹ̀ tọ̀ ọ́, bí ọ̀rọ̀ kò bá tóbi àkàwé rẹ̀ kì í pọ̀. Wọ́n ti ń mú ìyàwó ní abà Àkànbí ilẹ̀ ti ta sí i. Wọ́n ti ń fẹ́ aya fún ọmọ, má-le-gbàgbé ní ti Ṣùbòmí àti Monílọ́lá. Ojo rọ̀. Pẹpẹyẹ sì tún pọnmọ lọ́jọ́ tí à ń wí yìí. Ẹni tí ó bá sọ pé òwú ò tó ẹrù, ó dájú pé èyí tí yóò fi tanná ló mú. Ká má parọ́, ìgbéyàwó tó lárinrin gan-an ni.

Ìgbéyàwó ku ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n ti ń ri àtíbàbà alárìmọ́lẹ̀ ràgàjì kan báyìí. Nígbà tí wọ́n rì í tán àfi bí ẹni pé gbogbo ìlú ló ń bọ̀ wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Àwọn àga tí wọ́n to sábẹ́ rẹ̀ pátá ni wọ́n wọṣọ sí lọ́rùn láìṣe èèyàn. Àwòdami ẹnu ni àwọn ará Abà Àkànbí ń wo àwọn àga tó wọṣọ. Tọmọdé tàgbà ló ń ṣèèmọ̀ pé nígbà tí wọ́n fi ọjọ́ mẹ́ta ri àtíbàbà, ọjọ́ ìgbéyàwó gan-an yóò gọntíọ.

Bàbá Monílọ́lá ló farí gá pé dandan ni kí ọmọ rẹ̀ àti Ṣùbòmí wá ṣe ìgbéyàwó wọn nílùú tí wọ́n forí òun sọlẹ̀ sí. Ṣe ẹni a bá fẹ́ fọ́mọ lọ́wọ́ rẹ̀, ó di dóólè ká bá a fẹ́ ohun tó bá ń fẹ́. Baba ọmọ ló lọmọ,ìrùkẹ̀rẹ̀ ló lọmọ Ọ̀rúnmìlà. Ó kú ọ̀sẹ̀ kan ni ilé bàbá Monílọ́lá ti di ọ̀tun. Wọ́n tún un ṣe tí ó rẹwà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ogún ọdún tí wọ́n ti kọ́lé náà nígbà tí ó rí àtúnṣe, bí ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ló wá rí. Owó ń tún nǹkan ṣe!

Onírúurú ọ̀bẹ là á rí lọ́jọ́ ikú erin. Àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn ló péjúpésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Àwọn ará Abà Àkànbí náà mọ̀ pé àwọn gbàlejò. Ìlú Òyìnbó ni ọkọ ń gbé àmọ́ ìyàwó ló jẹ́ kó wálé nígbà tí Sàlàkọ́ ìyẹn bàbá ìyàwó kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò fẹ́ kí àbúrò ọkọ rọ́pò Ṣùbòmí.

Ilé ìtura tí Ṣùbòmí gbà fún òun pẹ̀lú ìyàwó ẹlẹ́sẹ̀-osùn ni wọ́n morí lé bí wọn ṣe kúrò lójú agbo. Ibẹ̀ ni ó ti fẹ́ jẹ a-dùn-má-dẹ́ẹ̀kẹ́.

Ó fẹ́ lọ sí Atan. Kó sì tún gbà ibẹ̀ dé Adó, kí ó tún fẹsẹ̀ kan dé Ìgbàrà-Òkè. Kò wá sinmi ní Sùúrùlérè. Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ bí i ti tòlótòló pé lẹ́yìn súù kí adìẹ ó fò ló kù.

Oúnjẹ tí wọ́n gbé fún wọn ni wọ́n jẹ tán ni gbágbá bá rú. Kokoko dún lára ilẹ̀kùn. Àwọn méjèèjì lérò pé lára àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn pè lórí aago pé kí ó mú ọtí ẹlẹ́rìndòdò wá ni. Àwọn ìgìrìpá méjì kan ló wọlé pẹ̀lú ìbòjú. Ẹnikẹ́ni kò lè dá wọn mọ̀. Oúnjẹ tí Ṣùbòmí tí ń palẹ̀mọ́ àtijẹ kíá páà ni wọ́n bá a jẹ́. Ìrìn-àjò tí ó ń múra àti rìn, ní pápàpá ni wọ́n bá a rìn ín. Bí Monílọ́lá bá tilẹ̀ fẹ́ gbọnmú kì í ṣe lójú irin tútù. Ariwo wo ló fẹ́ pa nígbà tí wọ́n ti fi aṣọ dí i lẹ́nu pinpin. Jìnnìjìnnì ti bo ọkọ náà, ìdí rẹ̀ tí domi.

Àwọn Atiláawí júbà ehoro bí wọ́n ti ṣiṣẹ́ ibi wọn tán. Ariwo Ṣùbòmí tí wọ́n gbọ́ ló ta àwọn òṣìṣẹ́ lólobó pé nǹkan ń ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn ń bèèrè pé ṣe wọn kò ṣe wọn ní jàǹbá? Monílọ́lá kàn ń wa ẹkún mu ní tìrẹ ni. Ẹnìkan sún mọ́ ọn, ó ní màdámú, ṣé wọn ò fọwọ́ kàn yín ṣá? Kàkà kí ó fèsì, ẹkún rẹ̀ tún lékankà si.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *