Ó Di Pẹ́ Ǹ Túká

Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé awọn ẹranko ló kọ́kọ́ dáyé ṣáájú àwa ènìyàn. Èyí jẹ́ kí àǹfààní wà fún àwọn ẹranko láti máa hùwà àti ṣe bí ènìyàn láyé ìgbà kan.

Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni Eku àti Ológbò (ẹni tí àdápè rẹ̀ ń jẹ́ o-ní-ogbò). Ọ̀rẹ́ àwọn méjéèjì dàbíi ọ̀rẹ́ òṣùpá àti ìràwọ̀, bí ìgbín fà, ìkaraun á gbá yá á kẹẹrẹkẹ tèle. Wọ́n ní ilé kan tí wọ́n jọ ń gbé ṣùgbọń inú apẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ń lò sí jù. Ìdí ni pé nígbà tí ìyà wọn  bí wọn, inú apẹ̀rẹ̀ ló kó wọn sí. Nítorí náà, ibi tí ẹ bá ti rí ìkíní ni ẹ ti ma rí ìkejì láì fọ̀tá pè.

Fún ìsúnmọ́ra wọn, ìjọra ma ń wà nínú ìṣe wọn. Tí Ológbò bá lọ sí ọjà láti lọ ra oúnjẹ, Eku ni yóò gbọ́ oúnjẹ náà bí ó bá dé.Bí ó bá di àṣalẹ́, wọn máa ń di ọwọ́ ara wọn mú ṣe fàájì kiri bí ẹni ń tage. Táyéwò àti Kẹhìǹdé ni àwọn ènìyàn tilẹ̀ ń pè wọ́n ní àkókò yìí nítorí aṣọ kan náà ni wọ́n maá ń wọ̀.  

Lọ́jọ́ kan, bí àwọn ọ̀rẹ́ méjì yìí ti ń ṣeré kiri, Eku sọ̀rọ̀, ó ní, ‘ọ̀rẹ́ẹ̀ mi, n bí o mọ̀ pé ibi ayé bá yí sí ni ó yẹ a bá wọn yí sí, ayè ọ̀làjú la wà yí o, jẹ́ ka wá orúkọ ẹ̀fẹ̀ tí a ó ma fi pera wa’,  Yorùbá ni orúkọ tó bá wu ni là á jẹ́ lẹ́yìn odi’. Ológbò mirí sókè sódò láti fọwọ́ sí i. Wọ́n pinnu láti wá orúkọ náà kí ọ̀sẹ̀ náà tó parí.

Bí eré bí eré, Ológbò ni òun yóò máa jẹ́ Coss. Eku náà lóun ò ṣánwọ́ wá, ó ní kí ó ma pe òun ní Moss. Inú àwọn méjèjèjì dùn fún àwọn orúkọ yìí, ìgbà tí wọ́n bá ti wà papọ̀ ni wọ́n ma ń pe ara wọn lórúkọ yìí kí ẹnikẹ́ni má ba ṣe ẹ̀dà rẹ̀. Ọ̀rẹ́ wọn túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i.

A kìí rìn kórí má jì. Gbólóhùn asọ̀ maá ń wáyé láàrín wọn, wọ́n á fi pẹ̀lẹ́kùtù parí ẹ̀ láìsí etí kẹta níbẹ̀ ṣùgbọ́n ìjà ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ láàrín wọn lówǔrọ̀ ọjọ́ kan. Ìwà ìbàjẹ́ àt’ọ̀kánjúà Moss ló dá ìjà yí sílẹ̀.

Bí ó bá ti dáná, á ṣa gbogbo ẹran òun ẹja inú ìkòkò ọbẹ̀ pátá láì kù kan. Bí Coss bá bèèrè ìdí tó fi fẹ́ so ẹẹran mẹ́ran kàn kan pa. Ó ní dókítà ló ní ẹran áti ẹja ni kí òun ma jẹ lóòrè kóòrè kí òun ba lè pẹ́ láyé dáadáa. Coss kìlọ̀ fún-un láti jáwọ́ nínu ìwàkíwà tó lè ba ọ̀rẹ́ wọn jẹ́ ṣùgbọ́n Moss kọ etí ọ̀gbọ́in síi. Ìwà yìí ti wá di bárakú fun.

Inú bí Coss gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tó fi lọ já bá Moss níbi tó gbé sùn fọnfọn sí. Ọmọ àlè lá á rínú tí kò ní bi. Ó fa Moss ní ìrùdí (ẹ̀rù ma ń bàá bí ẹnikẹ́ni bá ṣe èyí fún-un). Kíá, ó fò làì, ó tọ kébé sílẹ̀, ó fẹsẹ̀ fẹ, ìfẹ́ a féwé! Ẹlẹ́ṣẹ̀ ń sáré nígbà tí à ń lé e. Ó ti rántí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀.

Bí Moss ti ń sáré àsápajúdé ló ń jẹ orúkọ Coss lẹ́nu pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ pé kí ó má ṣe òun léṣe. Bí ó ti kéré tó yìí, eré burúkú wà lẹ́sẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n bí Moss bá ní kí òun bòó mọ́lẹ̀, á kú fin-ín fin-ín.

Moss ti dalẹ̀ ọ̀rẹ́, ó sì tún ti paná ìfẹ́ tí ń jó láàrín wọn. Nítorí ìdí èyí, Coss pinnu láti máa dáná tirẹ̀ lọ́tọ̀. Ó ní ilé nìkan ló pa òun àti ẹ̀ pọ̀. Àti kékeré ni Coss ti kórǐra ìrẹ́jẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó ma ń fi í kọrin sí Moss létí bí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò kàá sí, bí ìsọkúsọ ni lójú rẹ̀.

Kí ilẹ̀ ọjọ́ náà tó ṣú ni Coss ti lọ ọjà. Ó ra ikọ̀ àti ìwọ̀n ẹja. Ìgbà tó di ọjọ́ kejì, ó kọrí sódò lọ pẹja. Kò tilẹ̀ pẹ́ tó dé bẹ̀, ó rí ẹja ńlá mẹ́ta àti wẹ́wẹ́ mệrin pa, inú rẹ̀ dùn dé ìbàdí. Kódà, bí wọ́n bá wa ọkọ̀ ojú omi nínú rẹ̀, kò leè rì.

Coss kó igi jọ, ó ń yan áwọn ẹja rẹ̀. Moss ní tirẹ̀ ti jáde lọ. Kí ni yóò ṣe bí kò bá rí ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílẹ̀? Bí ó ti ń wọlé bọ̀ ló ti ń gbóòórùn. Imú rẹ̀ ń jó, bẹ́ẹ̀ ni ètè rẹ̀ ń gbọ̀n. Ó ní ‘ta ni ó lè má a yan ẹja lágbègbè yìí?

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọ inú ilé lọ, ó rí ibi tí wọ́n ń gbé yan ẹja lórí iná. Ó ní “hẹ̀n-ẹ́n ẹǹ, Coss tilẹ̀ ti gbẹ̀yìn gbẹbọ jẹ lọ odò, kò tilẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá ebi ń pọmọ ẹnì kankan”. Bí ó ti ń dá sọ̀rọ̀ nimú rẹ̀ ń jó bí ìgbà tí wọ́n bá pàlù fún òkòtó. Ìwà olè àti wọ̀bìà ti wọ̀ọ́ lẹ́wù, bí ó ti ń súnmọ́ ẹja ló n wẹ̀yìn wò, oní-ǹnkan ti lọ odò lọ pọnmi.

Moss ló jẹ́ ka mọ̀ pé ẹja oníyọ̀ ni. Àjẹwọra àti Àjẹ pọ́nnu lá ló ń fi wọ́n jẹ,ta ni yóò jẹ ẹja odò tí kò ní pọ́nu lá ? Níṣe ló fẹ̀ sílẹ̀ bí ọba ìdun. Ká máà déènà pẹnu, ó fi gbogbo rẹ̀ lánu tán porogodo. Ó n wọ́ dé inú apẹ̀rẹ̀ tó maá ń sùn sí.

Coss kò tètè rómi pọn lódò nítorí èrò pé pitimù sódò. Yóò tó wákàtí kan síi kí Coss tó wọlé. Bí ó ti wọle, ìdí ẹja rẹ̀ ló tààrà.. “Héè!Àwọn ẹja mi ti rá féú” nigbe tó fi bọnu! À-fi-ǹ- kan-pe-ǹ- kan níí ḿ ba ǹ-kan jẹ́ lọ̀rọ̀ ọ̀un rí, ọ̀rẹ́ ànàá kò jọ tèní mọ́.

Ọ̀dọ̀ Moss ni ó kọ́kọ́ ronú lọ,. Ẹsẹ̀ Moss bọ̀nà. Ẹni jalè lara í fun. Bí Coss ti ń wo ìpàkọ́ rẹ̀ níwájú lòun náà gbá kùrùkẹrẹ tẹ̀lé e. Ó ti ṣèlérí pé bí ọwọ́ òun bá lè tẹ Moss, pípa ni. A-wí-fúnní-kó-tó-dáni, àgbà òmùjà ni. Àfojúdi ìlẹ̀kẹ̀ sì rèé,  níí jẹ́ ẹrú kò ní.

Ó le bá ṣùgbọ́n bí ó ṣe ní kí òun mú Moss, kọ́tọ́ ló sá wọ ihò kan tó wà ní ìkọjá ilé wọn díẹ̀. Coss dúró síwájú ihò náà nírètí pé Moss yóò tètè jáde kúrò nínu ooru náà. Ìgbà tó retí remú pẹ̀lú ebi nínú ló pẹyìn dá nírètí àti pa á yán-án-yán lọ́jọ́ tí ó bá fojú gáání rẹ̀ Láti ìgbà yìí náà ni ọ̀rọ̀ àwọn méjéèjì ti di egungun ẹja lọ́rùn ara wọn. Moss fisó kékeré bàdíí jẹ́ tó fi di pé wọ́n túká

Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé:

Ọláyàtọ Ọláolúwa jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti persian cat corner image persiancatcorner.com/can-persian-cats-catch-mice/

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *