Ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọdún tó wuyì tó sì ṣe pàtàkì ní ilé-ifẹ̀, ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe ọdún yìí. Ọdún Ọlọ́jọ́ yìí ló tóbí jùlọ́ nínú gbogbo ọdún tí wọ́n máa ń ṣe ní Ilé-ifẹ̀, ọdún Ọlọ́jọ́ yìí ni wọ́n máa ń ṣe ní ìrántí Ògún tí ń ṣe òrìṣà irin. Ọdún Ọlọ́jọ́ le bọ́sí oṣù kẹsàn tíí ṣe (oṣù ọ̀wẹ̀wẹ̀) tàbí oṣù kẹwà tíí ṣe (oṣù Ògún). Àlàkalẹ̀ ni yóò sọ ọjọ́ tí ọdún náà yóò bọ́ sí. Ìdí abájọ ni pé púpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe agbátẹrù ọdún Ọlọ́jọ́ náà ní ṣe agbátẹrù ọdún ọ̀ṣun Òṣogbo, bẹ́ẹ̀ sì nì yìí ó ní iye ọjọ́ tí wọ́n máa ń kà kí wọ́n tó ṣe é kí ó má baà fi orí gbára wọn.

Oríṣiríṣi ètò ni ó máa ń wáyé kí ó tó di ọjọ́ ọdún yìí, ètò tí a mọ̀ sí Gbàjúre. Gbàjúre jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó máa ń wáyé láàárín àwọn àgbà Ifẹ̀ ní àsìkò ọdún Ọlọ́jọ́, ó jẹ́ ètò kan tó máa ń lọ láàárín àwọn àgbà Ifẹ̀ láti fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ ọdún Ọlọ́jọ́. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí wón bá parí ètò tàbí ìgbésẹ̀ yìí, kábíyèsí máa wà ní ìpèbí fún ọjọ́ méje láìjẹ láìmu. Àkókò yìí jẹ́ àkókò ìyàsọ́tọ̀ fún Ọ̀ọ̀ni tó bá wà lápèrè, kò ní rí ìyàwó kankan, ọmọ, ẹbi, àwọn olóyè àti ará ìlú àyàfi àwọn ìsòrò àti àwọn abọrẹ̀ tí ó bá ń se ìpèsè fún ní àkókò náà. Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé àkókò yìí ni Ọ̀ọ̀ni máa ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ònilẹ̀ tí yóò sì i gba agbára; àwọn agbára wíbẹ̀ jẹ́bẹ̀, àwọn agbára tótó láti fi ṣe ìjọba gẹ́gẹ́ bí àrólé Odùdùwa. Yóò wà ní ìpèbí láti le wà ní mímọ́ àti láti gba agbára tí yóò fi gbé Adé Aàrè. Ní àsìkò ìyàsọ́tọ̀ ọjọ́ méje yìí, àwọn ètò àti àríyá mìíràn yóò ma lọ fún ìpalẹ̀mọ́ Ọlọ́jọ́ nínú ààfin láàrin àwọn àgbà Ifẹ̀, Oṣògún àti abọrẹ̀ tàbí ìsòrò tọ́rọ̀ bákàn. Oṣògún yìí jẹ́ aṣojú Ògún, ìwàrà lóni Oṣògún.

Ọjọ́ tí Ọ̀ọ̀ni bá máa jáde ní ìpèbí ni ọjọ́ ọlọ́jọ́ máa ń bọ́sí. Ní ọjọ́ yìí, kábíyèsí yóò dé Adé Aàrè lọ sí Òke-Mòògún pẹ̀lú Oṣògún àti àwọn ìsòro tí ọ̀rọ̀ náà bá tún kàn. Òke-Mòògún yìí ni kàbíyèsí yóò ti máa fi ẹnu rẹ̀ wúre àláfíà, ìlọsíwájú àti láti súre fún àwọn ará ìlú àti láti ṣe àwọn ètùtù kọ̀ọ̀kan torí pé Adé Aàrè yìí jẹ́ Adé Ìṣẹ̀ǹbáyé ti ìlú Ilé-Ifẹ̀, ó pọn dandan kí ọba dé Adé náà.

Adé-Aàrè yìí jẹ́ Adé tí Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀ jogún lọ́wọ́ baba ńlá wọn Odùduwà, Adé yìí nìkan ló jẹ́ Adé àṣẹ tí Ọ̀ọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ jogún lọ́wọ́ baba ńlá baba rẹ̀. Lẹ́yìn ọdún Ọlọ́jọ́, àwọn nǹkan tuntun mèremère yóò maa sẹlẹ̀, àláfíà yóò jọba, ìlú yóò ma tùbà tùṣẹ. Ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọdún tó fi àṣà, ìṣe àti ìgbàgbọ́ àwa Yorùbá hàn dáadáa. Ọdún náà jẹ́ “Ọdún Ògún” wọ́n sì gbàgbọ́ pé tí wọn kòò bá ṣe ọdún yìí, Ògún kò ní jẹ́ kí àwọ́n sinmi.

Nípa Òǹkọ̀wé

Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.

     

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *