Àrà mí ò rírí, mo rórí Ológbò látẹ
Ajá wẹ̀wù, ó rósọ, ó tún gbọ́mọ́ dáni
Èké dáyé, áásà dàpòmú
Huuuuun kò jọmílójú
Torí mo ti róhun tó ju bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé
Ṣe Adágbà jẹ́ Raufu kan ò sí
Rádaràda kì í báni lágbà
Kékeré ló tí n báni lọ
Ṣùgbọ́n sá o, ṣe bó ṣe yẹ kórí nù-un?
Ni tòótọ́ mo kéré lójú
Ṣùgbọ́n ìrírí ti tètè sọmí dàgbà
Mo ti rìn jìnà nínú ayé
Bẹ́ẹ̀ kò sí ohun ojú mi yìí kò rírí
Kò sóhun tétí mi ò gbọ́ rí
Èyí tí mí ò sí níbẹ̀ ní mó ti bá lárọ̀bá baba ìtàn
Ṣe ọ̀kànlélọ́gọ́ta mí rè é lókè eèpẹ̀
Wọn tí sọ̀tàn ọmọ ìyá mẹ́ta tí
Baba wọn fẹ̀mí ẹ̀ gbòmìnira fún-un fúnmi
Àmọ́ mo ti rìn fáá débi ọmọ ìyá mẹ́ta òhún
Ti kú sóko ìwọ̀fà látàrí àìsọkan
Síbẹ̀ àwọn ara ilé wọn tún jó lọ́jọ́ ìsìnkú wọn.

Mo rìn títí mo débìkan ìbìkàn
Níbi ilẹ̀ wọn ti gbé lọ́ràá
Tójò ń rọ̀ nígbàdégbà sílẹ̀ fún wọn
Ṣùgbọ́n níṣe ná ń fọmọ àparò sábẹ́ gbinkà láti nnkan bí ogójì ọdún
Tí wọ́n ń fàáyá sọ́ko lati ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn
Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ isu ńta lébè wọn
Àgbàdo yọmọ bọ̀ọ̀kùbọ̀ọ̀kù láàlà
Àmọ́ kàkàkí wọn kérè oko
Ní ṣe na tún ń fi sébè kó bàjẹ́
Torí kán lè rówó gbà nílùú òdìkèji
Mó ṣe ìrìnàjò fáá de ìlú kán tobìnrin solorukọ
Tó jẹ́ àwọn ná lágbára jù láàrin akẹgbẹ́ wọn
Síbẹ̀ nílùú ti à ń sọ yìí
Láti bi ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn
Mọ́namọ̀na ni Iná mọ̀nàmọ́ná wọn
Gbágagbàga ni gbogbo ọ̀nà wọn
Ahoro ni Gbogbo ilé-iṣé wọn da
A ní mo ti rìn fáá
Debi tọmọdé tàgbà ìlú yìí ńgbé ji ríyà he
Tó jẹ́pé kàkà kí wọ́n wọ́nà àbáyọ sọ́rọ̀ wọ́n
Orin ọ̀la a dára ná ń mu bọnu lójoojúmọ́
Bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run ṣàánú wọn.

Mo rìn títí dágbéègbè kan nílùú Ajíriyà
Níbi agbésùmọ̀mí tí ń pará ìlú bí eesin
Ibi àwọn ajínigbé tí ń wọlé gbọ́mọ báálẹ̀
T'álọ kólóhunkígbe tí ń sọtú lójú gbangba
Ìlú táwọn ààrè tí ń fọwọ́ lalẹ̀ fónílé
Bẹ́ẹ̀ni wọ̀n ò gbọdọ̀ gbin
Mo dé ààyè kan ààyè kán nílùú yìí
Níbi àwọn àgbààgbà ti ń fọmọdé sàwúre
Níbi àwọn ọ̀dọ́ ti ri gbájúẹ̀ bí iṣẹ́ ọpọlọ
Táwọn òṣìṣẹ́ ti rówó ìbọ̀nú bí ẹ̀tọ́
Níbi wọn tí sọ fàyàwọ̀ dòwò gidi
Gbogbo ẹ torí àti là lóòjọ́
Láàyè tí mó ń sọ yìí
Wọn lẹ́sọ̀ọ́ síbẹ̀ kò wù wọ́n ri àfi tẹni ẹlẹ́ni
Wọ́n gbàgbé pé ẹ̀sọ́ Ẹlẹ́ẹ̀ṣọ́ bí ò soni a sì fúni.

Bẹ́ẹ bá bámi rìn ni
N ò bá fìlú kan hàn yín
Níbi etí mi ti gbọ́tàn ìbánujẹ́ tó gbẹ̀rín lẹ́nú mi
Níbẹ́ẹ̀ ọ̀gá Ọlọ́pàá ó mọsẹ́
Tí wọn ò sì yọ́ ọ́ níṣẹ́
Àwọn Ìjòyè ò kún ojú òsùnwọ̀n
Bẹ́ẹ̀ wọn ò rọ̀ wọ́n lóyè
Àfi kí wọ́n tún fokùn kún apá wọn
Ìbá jẹ́ ẹ tèlé mi debi ilu tódo Congo àti Naija ti pàdé
A ó bá ríbi ilé ìjósìn tí pọ jaburata
Àmọ́ kò sí ìbẹ̀rù Olúwa lọ́kàn àwọn Olùjọ́sìn
Àlùfáà ń bá ìyàwó ọmọ ìjọ lásepọ̀
Ọmọ ìjọ ń sààgùn s'álùfáà
Síbẹ̀síbẹ̀ ‘funfun nẹnẹ ninu àwa’
Ni gbogbo won ń kọ lórin.

Bẹ́ẹ ẹ bámi lọ, a ò bá rìn dé ìlú kan ìlù kàn
Níbi ebi àjàgà fọwọ́ mẹ́kẹ́ ti ń pa ará ìlú
Táwọn aṣáájú ilú sì ń kọrin 'Bámúbámú ni mo yó'
Níbi òùgbẹ tí ń pa ará ilú
Síbẹ̀ àwọn olórí ìlú ti ju kọ́kọ́rọ́ kànga sápò
Ṣùgbọ́n orin 'ìwọ la fi ràn' àti
‘Má ba iṣẹ́ rẹ lọ, ó ń tẹ́ wa lọ́run’
Làwọn èèyàn ibẹ̀ ńkọ
Lájọ̀dún mẹ́rin mẹ́rin tán ńṣe
Mélòó ni mo fẹ́ sọ, mélòó mo fẹ kà
Nínú eyín adípèlé ìlú kan ìlù kàn
Tán ń pèní Nàìjíríà
Níbi wọn ń gbé fojoojúmọ́ ríyà
Táwon ọmọ, ará ibẹ̀ ń jìyà tún jewé ìyá
Síbẹ̀ ọjọ́ gbogbo ná ń sàríyá!

Nípa Òǹkọ̀wé

Mustapha Sherif jẹ́ olùkọ́ èdè Yorùbá pẹ̀lú àjọ Teaching Service Commission ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *