Ewì

Ọmọ Kàyéfì | Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀

Ìdùnnú a ṣubú lu ayọ̀ 
Lọ́jọ́ a bá bímọ tuntun sáyé 
Tẹbítará a kí túńfúlù káàbọ̀.    
Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ 
Tóṣù ń gorí oṣù  
Ìrètí bàbá ni kọ́mọ ó dàgbà 
Ìrètí ìyá ni kọ́mọ ó dẹni gíga. 
Àmọ́ ọmọ kọ̀ kò rá 
Túńfúlù ìjọ́sí fárí gá kò rìn. 
Àwọn tí wọn dìjọ dáyé 
Gbogbo wọn ló ti ń sáré kiri 
Àwọn tó dìjọ jẹ́ irọ̀ 
Lòbí ti ń jẹun wọn. 
Ìyá ń tójú bọlé aláàfáà 
Bàbá ń fọ̀rọ̀ lọ aládúrà 
Wọn ò gbẹ́yìn nílé oníṣègùn
Nítorí kọ́mọ ó lé dide nàró 
Ọmọ kọ̀, kò rá kò sì tún rìn. 
Àsẹ̀yìnwá Àsẹ̀yìnbọ̀ ìgbìyànjú 
Wọ́n ní kí wọn ó béèrè lọ́wọ́ ìyá
Wọn ni kí wọn ó tẹ baba nínú. 
Torí ọmọ tó kọ̀ tí kò rìn yín 
Díẹ̀ lọ́wọ́ ìyá díẹ̀ lọ́wọ́ baba. 
Kò pẹ́ kò jẹ́ jìnà 
Ọmọ tí a wí bẹ̀rẹ̀ sí í rìn 
Ọmọ ọ̀hún dàgbà lójú òbí ẹ̀ 
Ọmọ ọ̀hún pọ́dún méjìlélọ́gọ́ta 
Kò ì lè dá bùkátà gbọ́
Ọmọ tọ́jọ́ orí rẹ̀ kìí ṣe kèremí 
Tí ò mọ dàbìdábí 
Kàyéfì ńlá ló jẹ́ fára àdúgbò. 
Ọmọ yìí ó le dóhunkóhun ṣe 
Bọ́mọ ọ̀hún ò bá dọ́dọ̀ ará ilé kejì 
Kò le rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu lójúmọ́ 
Ìkòríta mẹ́ta tó ń dààmú àlejò 
Lọ̀rọ̀ ọmọ kàyéfì tákéwì ń wí. 
Àwọn olóye lọ̀rọ̀ mi le e yé 
Ṣàṣà èèyàn ló le mọ̀dí àṣàmọ̀

Nípa Òǹkọ̀wé:

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Àwòrán Ojú Ìwé Yìí Jẹ́ Ti Culture Trip.

Related posts

Kí Akọni Tó Di Akọni | Akínrìnádé Fúnminíyì Isaac

atelewo

Ẹ wa̒a̒ wẹ̀si̒n ara̒ ìbàdaǹ! | Fẹ́mi Àjàkáyé

atelewo

B’ọ́bẹ̀ ẹ bá dùn àti ewì míràn | Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀

Atelewo

1 comment

Ọ̀rọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Olóòtú — Ìpalẹ̀mọ́ Pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Ọdún – Àtẹ́lẹwọ́ November 17, 2022 at 8:49 am

[…] lára àwọn iṣẹ́ náà ni Ọmọ kàyéfì láti ọwọ́ Sheriffden Adeola Ogundipe, pàtàkì iṣẹ́ yìí àti ohun tí òǹkọ̀wé ń kọ sí ọmọ aráyé ni pé […]

Reply

Leave a Comment