Nípa akitiyan wá láti ṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ni a ṣe bere Àkójọpọ̀ àwọn ìtàn, ewì, àti àwòrán Ọlọ́dọdún.

Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú fún ìwé ‘Adéjọké ará Ìjílèje—Àkójọpọ̀ ìtàn kéékèèké Adébáyọ Fálétí,’ Òjọgbọ́n Ọlátúndé O. Ọlátúnjí kọ wípé: “Àwọn ọmọdé ni Adébáyọ Fálétí fi perí àwọn ìtàn tí a kójọ sínú ìwé yìí láti kó wọn lógbón. Nítorí ìdí èyí, mo fi ìwé yìí júbà gbogbo ọmọdé orílẹ̀ èdè yìí ní ìrètí pé wọn yóò ní ọgbọ́n tó yè kooro láti fi èdè abínibí wọn ṣe ohun àmúṣọgò gẹ́gẹ́ bí Adébáyọ Fálétí…”

Ọdún 1980 ni Òjọgbọ́n Olatunji kọ àwọn àwọn ọ̀rọ̀ wónyìí. Láìsí àní-àní, ìdàgbàsókè kékeré kọ́ ni yóò ti dé bá àwọn tí Òjọgbọ́n náà pé ní ọmọdé nígbà náà. Wọn yóò ti da Bàbá àti Màmá. Àmọ́, ǹjẹ́ Ìtẹ̀síwájú púpò tí dé bá ìlò èdè Yorùbá láti ìgbà náà?

Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ni o ṣokùnfà ìdásílè Ègbé Àtélewọ. Àwọn àfojúsùn wa jẹ́: 1. Láti pèṣè ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ati ọ̀dọ́ leé máa kopa pẹlú oríṣiríṣi ẹya aṣa àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ẹ̀kọ́, ìfọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ ati ṣi ṣe ìpàdé déédé. 2. Láti ṣe àgbékalẹ̀ ibi tí a ti má ṣe àkọsílẹ̀ ati ìpamọ òye àṣà Yorùbá ìgbà àtẹ̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa. 3. Tí ta àwọn èyàn jí sí ìfẹ́ lítíreṣọ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíjẹ kí ìwé lítíreṣọ̀ Yorùbá wà nlẹ̀ fún tità àti ṣíṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ní èdè Yorùbá.

Nípa akitiyan wá láti ṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé titun ni a ṣe bere Àkójọpọ̀ àwọn ìtàn, ewì, àti àwòrán Ọlọ́dọdún. A sì ń ṣe àtẹ̀jade àwọn oǹkọ̀wé lórí èrọ káyélujára. Ọdún méjì sẹ́yìn ni a tẹ Àkójọpọ̀ Kínní. Lénu ìgbà náà sì ìsinsìnyí, àwọn àgbà oǹkọ̀wé èdè Yorùbá mẹ́ta—Àwọn Alàgbà Adébáyọ Fálétí, Akínwùmí Ìsọ̀lá, áti Ọládèjọ Ọ̀kẹ́dìjí—ni wọ́n ti pa pò dà. (Kí Ọba òkè wo ilẹ̀ àti ọ̀nà tí wón fi sílè!) Àkójọpò wa ti ọdún yìí yóò ṣe àyẹ̀sí àwọn Bàbá wọ̀nyí. A sì ń gbára dì láti ṣe ìdíje ní orúkọ wọn. Ẹ kú ojú lọ́nà àwọn ètò wọ̀nyí!

Títí da ìgbà náà, e tẹ́wọ́ gba ìpèsè kékeré yìí.

Àwa la ó máa wá, èyin la ó sì máa bá!

Ẹ kú àsìkò yìí!

ÈGBÉ ÀTẸLEWÓ

Ìtọ́ka

  1. Ọ̀rọ̀ Olóòtú: Ìtọ́wò Àkójọpọ̀ Àtẹ́lẹwọ́
  2. Ìlànà fún Ìgbàwọlé: Àtẹ̀jáde Àtẹ́lẹwọ́ Apá kejì
  3. Ẹ̀rọ Ìránsọ | Kọ́lápọ̀ Ọlájùmọ̀kẹ́
  4. Ojúlarí | Rasaq Malik Gbọ́láhàn
  5. Nítàn kí o tó tán | Malik Adéníyì
  6. Lẹ́tà: Ọ̀rọ̀ Kẹ̀kẹ́ | ‘Gbénga Adéọba

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *