Ìdíje Ìwé Kíkọ

atelewo

ÌDÍJE ÀTẸ́LẸWỌ́ FÚN Ẹ̀BÙN LÍTÍRÉSỌ̀ YORÙBÁ TI ỌDÚN 2021

ÀTẸ́LẸWỌ́ jẹ́ ẹgbẹ́ tí a dá sílẹ̀ ni ọjọ́ kiní oṣù kẹfà, ọdún 2017 gẹ́gẹ́ bi ojútùú láti kọjú oríṣiríṣi àwọn ìpèníjà tó n d’ojukọ èdè àti àṣà Yorùbá. Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyan ni kò mọ̀’kọ mọ̀’kà ní èdè abínibí wọn, ó tún ṣe ni láàánú pé àwọn ìwé lítírésọ̀ Yorùbá tó jọjú kò wọ́pọ̀ mọ́n. Eléyìí sì ń ṣe àkóbá fún ipa wa láti dásí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń lọ lágbáyé pẹ̀lú òye abínibí wa.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó dé láti yí ǹkan padà, ÀTẸ́LẸWỌ́ wá láti ṣe àtúntò àti ìgbélárugẹ èdè àti àṣà Yorùbá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn wọ̀nyìí:

 • Láti pèṣè ibi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀dọ́ leé máa kópa pẹ̀lú oríṣiríṣi ẹ̀yà àṣà àti ìṣe Yorùbá látàrí ìdíje, ẹ̀kọ́, ìfọ̀rọ̀jomítoro ọ̀rọ̀ ati ṣíṣe ìpàdé déédé.
 • Láti ṣe àgbékalẹ̀ ibi tí a ti má ṣe àkọsílẹ̀ àti ìpamọ́ òye àṣà Yorùbá ìgbà àtẹ̀yìnwá àti láti máá lo ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé fún ìdàgbàsókè àṣà wa.
 • Tí ta àwn èyàn jí sí ìf́ lítíreṣ̀ Yorùbá latàrí ṣiṣe ètò ìwé kíkà, jíj kí ìwé lítíreṣ̀ Yorùbá wà nl̀ fún tità àti ṣíṣe àt̀jade àwn oǹk̀wé titun ní èdè Yorùbá.

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àfojúsùn wa, ÀTẸ́LẸWỌ́ fi àsìkò yìí kéde Ìdíje Ẹ̀bun Ọdọọdún Fún Lítírésọ̀ Yorùbá. Ìdíje yìí wà fún gbogbo àwọn òǹkọ̀wé èdè Yorùbá ti wọn ò tí tẹ iṣẹ́ (ewì, eré oníṣe àti àròsọ) wọn jáde rí.

A gbé Ìdíje yìí kalẹ̀ láti le kojú oríṣiríṣi ìpèníjà tó ń kojú ìwé kíkọ ní èdè Yorùbá bíi rírí àwọn atẹ̀wéjáde to mú’ṣẹ́ wọn lọkúnkúndùn, ìwé títà oun níní àwọn olùkàwé to ní ìfarajìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdíje yìí tún gbèrò láti dá ògo àṣà lítírésọ̀ Yorùbá padà, eléyìí tí ọ̀pọ̀ èèyan ti ṣe sàdáńkatà fún jákèjádò àgbáyé tẹ́lẹ̀rí.

Ìlànà

Fún àwọn tí wọ́n bá nífẹ sí fífi iṣẹ́ wọn ráńṣẹ́ sí ìdíje ÀTẸ́LẸWỌ́, wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀yìí:

 • Ìdíje yìí wà fún àwọn òǹkọ̀wé tí wọn kò bá tí ì tẹ ìwé jáde rí ní èdè Yorùbá. Eléyìí túmọ̀ sí pé gbogbo iṣẹ́ tí ẹ bá fi ránṣẹ kò gbọdọ̀ tíí wà ni títẹ̀jáde, yálà nínú ìwé ni o tàbí lóri ẹ̀rọ káyélujára.
 • Ìdíje yìí wà fún àwọn òǹkọ̀wé tí ọjọ́-orí wọn jẹ méjìdínlógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
 • Dandan ni kí àwọn ìwé ìfiranṣẹ náà wá pẹ̀lú àmì lórí wọn. Fún ìraǹlọ́wọ́ ẹ wo ibí àti ibí.
 • Òǹkọ̀wé kan, iṣẹ́ kan.
 • Òǹkà ojú ìwé ìfirańṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ wà láàrin àádọ́ta sí ọgọ́rùn-ún. Iṣẹ́ náà gbọdọ̀ wà ni ìwé Microsoft Word.
 • Àwọn òǹkọ̀wé gbọdọ̀ fi orúkọ wọn, àdírẹ́sì wọn àti nọ́mbà ẹ̀rọ alágbéka wọn (WhatsaApp) si Ojú ewé àkọ́kọ́ ìfiránṣẹ́ naa.
 • Ẹ fi gbogbo ìfiránṣẹ yín ṣọwọ sí atelewo.org@gmail.com pẹ̀lú àkòrí rẹ ni ìlànà yìí: “Orúkọ Iṣẹ́ _Orúkọ Òǹkọ̀wé_Ìdíje Ẹ̀bùn Àtẹ́lẹwọ́ Fún Lítírésọ̀ Yorùbá”.

Àtẹ́lẹwọ́ ní àṣẹ láti má ka ìfiránṣẹ́ tí kò bá tẹ́lẹ̀ àwọn ìlànà òkè yìí.

Ìdádúró

A kò ni ka iṣẹ́ ti ó bá wọ’le lẹ́yìn ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kọkànlá ọdún 2020.

Àwọn Olùdájọ́

 • Àrìnpé Adéjùmọ̀ (Ọ̀jọ̀gbọ́n àti Olùdarí sẹ́yìn, Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ẹ̀dá Èdè àti Àwọn Èdè Ilẹ̀ Áfíríkà ti Fásitì Ibadan).
 • Odòlayé Àrẹ̀mù (Òǹkọ̀wé àti Amòye Àwùjọ)
 • Adélékè Adéẹ̀kọ́ (Ọ̀jọ̀gbọ́n àti Alága Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Àwọn Adúláwò Amẹ́ríkà ati Áfíríkà ti Fásitì ìpínlẹ̀ Ohio, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà).

Ẹ̀bùn

 • A ó ṣí’ṣọ lójú eégún àwọn olùdíje àkọ́kọ́ márùn-ún ti ọkan nínú wọn yóò sí gbégbá orókè.
 • Àwọn olùdíjé àkọ́kọ́ márùn-uń náà yóò jẹ ẹ̀bùn ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún Náírà àti pé wọn yóò tún ní àǹfàní láti tẹ ìwé náà jáde pẹ̀lú wa.
 • Òǹkọ́wé tó bá gbégbá orókè yóò gba ẹ̀bùn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta Náírà (N50,000), ẹ̀bùn ìwé àti àǹfàní láti tẹ ìwé náà jáde pẹ̀lú wa.

Ìwádìí

Fún ìwádìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìbáṣepọ̀, ẹ kàn sí egbeatelewo@gmail.com.
ÀTẸ́LẸWỌ́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE 2021

ÀTẸ́LẸWỌ́ Cultural Initiative was founded on the 1st of June, 2017 as a response to the many     challenges and threats facing the preservation and survival of the Yorùbá culture and language. Apart from the fact that most people nowadays cannot even read in their indigenous African languages, there is also a greater concern as regards the waning presence of quality literature materials in these languages. And this has no doubt impeded our ability to sufficiently and originally contribute to global discussions and solutions.

As a course changing initiative,  ÀTẸ́LẸWỌ́ is dedicated to the reviving and repositioning of the Yorùbá culture with the mission to:

 • Provide a platform for stoking interest and generating fulfilling engagements with the dynamics of the Yorùbá culture through competitions, lectures, dialogues and regular meetups.
 • Provide a platform for the documentation and preservation of Yorùbá ancient knowledge, culture and language in keeping pace with technological advancement.
 • Rekindle people’s interest in Yorùbá literature by organising readings, making Yorùbá literature available for purchase and publishing new voices in the Yorùbá Language.

In line with our goals and objectives, ÀTẸ́LẸWỌ́ has hereby announces the annual “ÀTẸ́LẸWỌ́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE.” The competitionis open to previously unpublished writers working in Yorùbá language in all genres, (including poetry, drama and prose).

The ÀTẸ́LẸWỌ́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE is instituted to address some of the problems–committed publishers, distribution, cultivating invested readerships, etc.–that creative writing in Yorùbá faces. The ÀTẸ́LẸWỌ́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE intends to rejuvenate the more than the century old, vibrant, universally praised, and unquestionably rich Yorùbá literary culture.

Guidelines

Those interested in submitting for this prize must adhere to the following guidelines:

 • The prize is only open to writers who haven’t published a novel, play, or book length collection of poems written in Yorùbá as at the time of this prize. This means that submitted works must not have been previously published anywhere, whether in physical book format, social media platforms or any digital book platform.
 • Writers interested in submitting for the prize must be at least of 18 years of age.
 • All entries must be properly tone-marked with correct diacritics. See here and here for suggestions of tools and apps to help you.
 • Writers are required to send in their manuscripts–around 50 pages (Times News Roman, 1.5 spacing, font size 12)– in a Microsoft Word document format ONLY.
 • The first page of the submission should contain personal information about the author: Name, Full Address, and Phone Number (WhatsApp).
 • All submission must be sent to atelewo.org@gmail.com with the subject in this format “MANUSCRIPT TITLE_WRITER’S NAME_ATELEWO PRIZE FOR YORUBA LITERATURE”.

ÀTẸ́LẸWỌ́ has the right to disqualify any submission that does not follow the stated rules above.

Deadline

We will not consider any manuscript submitted after November 30, 2020.

Judges

 • Àrìnpé Adéjùmọ̀ (Professor and former H.O.D Linguistics and African Languages, University of Ibadan).
 • Odòlayé Àrẹ̀mù (Writer and Public Intellectual)
 • Adélékè Adéẹ̀kọ́ (Professor and Interim Chair, Department of African American & African Studies, The Ohio State University).

Prize

 • There will be a shortlist of top 5 entries and 1 grand winning entry.
 • The top five winners will receive book gifts worth N20,000 each and a deal to publish their works on our digital publishing platform.
 • The grand winner receives the prize of N50,000, book gifts and a publishing deal.

Enquiries

For enquiries, support and partnership, send a mail to egbeatelewo@gmail.com

Longlist

 1. Ẹ̀dáọ̀tọ̀ Àgbẹ́níyì (Gbankọgbì Àròfọ̀)
 2. Agboọlá Àyándìran (Ó já sọ́pẹ́)
 3. Mustapha Sheriff (Orin Ewì Àkọdán)
 4. Oreọ̀fẹ́ Precious (Orí yeye)
 5. Aria Ajia Ọlánrewájú (Obìnrin Mẹ́ta Lóríta Mẹ́ta)
 6. Sodiq Lawal (Koowe Ń ké)
 7. Àríyọ̀ Sofiu Ìṣọ̀lá
 8. Huswat Adéṣeun (Àìfojúsùn)
 9. Ṣeun Adéjàre (Tẹní Kú Lógbé)
 10. Amos Ọlátúnjí Pópóọlá  (Akínkanjú Ọdẹ Nínú Igbó Àmọ̀tẹ́kùn)

Shortlist

 1. Ṣeun Adéjàre (T’ẹníkú Ló gbé)
 2. Amos Ọlátúnjí Pópóọlá (Akínkanjú Ọdẹ Nínú Igbó Àmọ̀tẹ́kùn)
 3. Sodiq Lawal (Koówè Ń kéé)
 4. Agboọlá Àyándìran (Ó Já Sọ́pẹ́)
 5. Mustapha Sheriff (Orin Ewì Àkọdán)