Ewì

Ìmọ̀ràn | Káyọ̀dé Akínwùmí

Ẹ wí f’ẹ́ni tí ń sáré owó

Pélé t’ówó kọ a máa wọ́

Ẹ rò f’ẹni tí ń kànlẹ̀kùn ọlà

P’ọlà òní lè má dò̩la

B’ẹni lówó lọ́wọ́ tó r’ogún ẹ̩rú

Béèyàn lọ́lá lọ́là tó yọ́gbọ̀n ìwọ̀fà

Ikú tíí p’ẹrú níí pa wọ́n

Isà òkú wọn kìí jìn ju tìwọ̀fà

Ẹ̀ bá wí f’Ọláìítán p’ọ́lá a máa tán

Ẹ̀ bá rò f’Ówónikókó p’óníhun tíí ku ni kù

Ohun tíí sìí ku ni kù náà nìwà

Bó o bá torí àtilówó tó o hùwà àìtọ́

Bórí bá ọ́ ṣé tó o gbó, ìgbẹ̀yìn rẹ ò le tọ́

Bó o bá torí àtilọ́lá tó o hùwà ìkà

B’ọ́jọ́ bá d’alẹ́, ẹ̀san ìkà lo máa ká.


Káyọ̀dé Akínwùmí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ́, ipele àṣekágbá. Káyọ̀dé fẹ́ràn ìtàn púpọ̀, a máa gbọ́ orin lọ́pọ̀ ó sì jẹ́ olùwòye lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ.

Related posts

Ẹnìkan Ò Layé àti ewì míràn | Ọládẹ̀jọ Hammed Ọ́

atelewo

Coro ló pojú kòró jẹ àti ewì míràn|Huswat Lawal

atelewo

Nípa wíwà àti nínú Òfo àti ewì míràn | Awósùsì, Olúwábùkúnmí Abrahamu

atelewo

Leave a Comment