Ewì

Orí | Akínyẹmí Muhammed Adédèjì

Àṣẹ lórí àwòrán yìí jẹ ti Olaseni Alexoni

Orí ni baálé gbogbo ara, balógun —
tí máa d’árà
Orí l'atọ́kùn ara,
Olóòótọ́ tí ń darí ìwà,
Awakọ̀ ti kii sìnà l'ójú 'gbó,
Orí mi gbé mi dé bi ire.

Orí ni apẹja tí kìí ṣi àwọ̀n dẹ,
Orí ni ọlọ́dẹ ti máa ń pa ikú àti ẹfọ̀n.
Orí ni baálé gbogbo ara, balógun —
tí máa d'árà. Kàkànfò gbogbo ìwà.

Orí mi, dákun darí ọ̀rọ̀ ẹnu mi
kín lè bàa máà rántí pé ẹyin lọ̀rọ̀.
Orí mi, darí ìwà mi, kín lè ba maa—
rántí pé àgbà lè jin ni sí kòtò.

Orí ṣe atọ́kùn
ìwà, ẹwà, àti ìgbé ilé aiyé mi.
Orí mi sìn mí débi ire—
Kín lè bàa bẹ́'gbẹẹ́ pé,
Kín lè bàa bá àgbà jẹun,
Kí ìṣẹ̀dá mi lé bàa suwọ̀n.

Orí mi gbé mi dé ibi ire.

Nípa Akéwì

Akínyẹmí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti National Training Academy ní Egypt, ó sì jẹ́ amòfin tó kàwé já láti University ní Ìlọrin. Akínyẹmí ń ṣiṣẹ́ fún Africanliberty.org gẹ́gẹ́ bí oníròyìn.

Related posts

Sùúrù (Orin Démíanù ọmọ Málì àti Ọba Náàsì) | Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim

atelewo

Ẹ Bọ̀wọ̀ F’ágbà Àti Ewì Míràn|Àrásí Kamaldeen Moyọ̀sọ́rẹ

atelewo

Ẹni Ayé ń Yẹ | Azeez Ọláìyá Yusuff

atelewo

Leave a Comment