Àpilẹ̀kọ

ÒWE: Ọsán já ọrún d’ọ̀pá | Sobowale Kazeem Olalekan

ÒWE

Ọsán já ọrún d’ọ̀pá.

 ÀKÍYÈSÍ

*Ọsán:- ohun èlò tí a fi ún se ǹkan ìjà tí a mò sí ọfà
*Ọrún:- orísi ọ̀pá kan tí ó seé ro sí òtún tàbí sí ósí, tí kò sì leè kán, bí óti lè wù kí a róo tàbí kí a tẹ̀ẹ́.

ÀLÀYÉ NÍ KÍKUN

Ọsán jẹ́ oríṣi okùn kan tí àwọn baba nlá wa fi máa ń ṣe ohun tí wón fi ń ta nkan ìjà tí a mò sí ọfà.
Ọrún ni ọ̀pá tí wón máa ń so ọsán mọ́, kíó tó di ohun tí won yóò fi máa ta ọfà.
Ẹ̀wẹ̀, Ọfà jé ohun ìjà olóró kan tí a pèsè pèlú igi pélébé elénu sónsó tí kò gùn jù ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà méjì àti ààbò.

ÌTUMỌ̀ ÒWE NÁÀ

Bí ọsán bá já kúrò l’ára ọfà, ọ̀pá lásán náà ni ọrún yóò dà; kò sì leè wúlò mọ́ gẹ́gẹ́ bíi ohun èlò tàbí nkan ìjà tí a fi ń ta ọfà.

ÀWỌN ÀKÓKÒ TÍ A MÁA ÚN LO ÒWE YÌÍ

Àwọn baba wa a máa pa owe yìí ní àkókò tí ènìyàn bá p’àdánù ẹni tí ójé igi-l’éyìn-ọgbà. Irúfẹ́ ẹni náà lè jẹ́ Bàbá tàbí ìyá ẹni; ó sì lè jẹ́ elòmíràn ti ó sún mọ́ ni pẹ́kípẹ́kí , gẹ́gẹ́ bíi olùrànl’ọ́wọ́ tàbí alábǎrò ẹni.
Bí ọrún se p’àdánù ànfààní rẹ̀ bí kò bá sí ọsán, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ènìyàn ṣe lè kọjú àwọn ìṣòro nínú ìgbìyànjú l’áti tẹ̀ Síwájú.

ÀLÀYÉ L’ÓRÍI ÀWON ÀSÀYÀN ÒRÒ INÚ ÀPILÈKO YÌÍ NÍ ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ

Ọsán:- a kind of tiny rope that is used for making a bow for arrows (it is also used for tying parts of a talking drum together.)
Ọrún:- a kind of flexible wooden stick to which a tiny rope (osán) is tied, in order to make a bow for arrows.
Ọfà:- an arrow that is being shot by a bow.
Òntàfà:- an archer; a person who shoot arrows with bow.

Related posts

Kọ̀lọ̀rọ̀sí | Khadijah Ọlájùmọ̀kẹ́ Kọ́lápọ̀

atelewo

Ǹjẹ Ìwọ ti ka Ìwé ‘Ọláọ̀rẹ́ Afọ̀tẹ̀joyè’? | Ọ̀rẹ́dọlá Ibrahim

atelewo

Ìgbéayé Bàbá Àmọ̀pé | Ọlájùmọ̀kẹ́ ọmọ Kọ́lápọ̀

atelewo

2 comments

Oyelami Siddiq July 23, 2018 at 9:53 am

Àkíyèsí pàtàkì!!!
Ọ da wípé ẹ ṣe àṣìṣe ni bi “…ọ̀pá lásán náà ni “ọfà” yóò dà;”.
Àtúnṣe
Ni “ọrún” yóò da

Reply
atelewo August 2, 2018 at 11:50 pm

Ẹ Ṣeun gan an fún àkíyèsí yín. A ti ṣe àtúnṣe.

Reply

Leave a Comment